Rice: Kò sí ìrẹsì lọjà mọ látàrí ibodè ti ìjọba tì pa - Ọlọja

Aworan Irẹsi wiwọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Ọpọ ile itaja irẹsi ni ojuko itaja ti Mile 1, ni Ilu Pọta lo wa ni titi pa latari igbese Ijọba lori aiko irẹsi wọle.

Alaga awọn ti o n ta irẹsi ni ọja naa, Anselm Nwachukwu ṣalaye fun ile iṣe BBC pe, pupọ ninu wọn lo ti pa ọja naa ti ti wọn si ti wa wọrọkọ ṣada.

O tẹsiwaju pe, titipa ti Ijọba ti ibode pa yii ṣe akoba pupọ fun idokowo wọn, nitori ko si irẹsi lati ta fun wọn.

Ninu ọrọ rẹ loti ṣalaye pe, ijọba ko ro ọrọ naa daada ki wọn to gbe igbesẹ ọhun, nitori ko si irẹsi lori igba ti o si mu inira ba eto okoowo wọn.

Àkọlé àwòrán,

Oluraja ati Olutaja iresi

Emeka Okameme ti o jẹ gbajugbaja oniṣowo irẹsi sọ wi pe aisi irẹsi ko jẹ ki ọja ya.

O ni ko si irẹsi lọja mọ koda eyi to jẹ tiwa n tiwa gan ko si ti o wa jẹ ki iye owo ti wọn n ta irẹsi lọ soke.

Ko ṣai mẹnuba ọpọlọpọ wahala ti wọn doju kọ ki wọn to ri eyi ti o wa lori atẹ bayii ra, ti o wa mu ọwọn gogo ba irẹsi.

Bayii owo gọbọi ni wọn n ta irẹsi lọja ti ko si din ni ẹgbẹrun lọna marundinlọgbọn ti ikeji si jẹ ẹgberun lọna mejilelogun naira.

Ṣe ṣaaju akoko yii ni wọn ti n ta ni ẹgbẹrunmẹtadinlogun naira fun irẹsi oke okun ti tiwa n tiwa si jẹ ẹgbẹrun mẹrinla naira.

Ẹnikan ti o n ta irẹsi sise, Brenda Owen sọ pe agolo irẹsi kan bayii ti di ọgọfa naira.

Àkọlé àwòrán,

Iresi

Koda wọn ni aisi irẹsi yii ti ṣakoba fun awọn ounjẹ miiran lori atẹ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba yoo maa ti ibode, wọn ti i ni ọdun 2003 ati Osu kẹfa ọdun 2018.

Ni bayii, iye ti wọn n ta apo agbado ti lọ soke lati ẹgbẹrun marun naira si ẹgbẹrun mẹsan naira.