Ondo Cow Death- Mùsùlùmí òdodo ni emi, mi ò kìí pa irọ́- Olu Ikare

maalu

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Maalu mẹjọ di oku ni Ikarẹ / Akoko ni eyi ti Olukarẹ ni ko ni ọwọ ara ilu ninu

Ó ṣeeṣe kó jẹ ohun tí wọn jẹ ló ṣekú pawọn ṣugbọn kìí ṣe ìlú lo pa wọn- Olukarẹ ti ilu Ikarẹ.

BBC ti ba Kabiyesi Ọba Akadir Momoh, Olukare ti ilu Ikare sọrọ lataari iṣẹlẹ maalu to ku ni ilu Ikarẹ, ni Ipinlẹ Ondo.

Oba Alayeluwa naa ṣalaye pe ilu ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Kabiyẹsi fidiẹ mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ṣugbọn ilu ko ṣe ohunkohun lati ba ẹnikẹni ja rara.

Oku Maluu

Oríṣun àwòrán, facebook

Àkọlé àwòrán,

Maluu ti ara san pa ni Ondo

Ninu alaye Ọba alaye naa ni wọn ti sọrọ wi pe, o ṣeeṣe ko jẹ ohun ti awọn maluu naa jẹ lo ṣe ku pawọn ṣugbọn kii ṣe pe boya ẹnikankan to ṣokunfa iṣẹlẹ naa.

Ori Ade ni lootọ oun ko si ni ilu nigba ti iṣẹlẹ naa ṣẹ ṣugbọn gbogbo rẹ ni wọn ti fi to awọn leti.

Kabiyesi ko ṣai mẹnubaa wi pe, gẹgẹ bi Musulumi ododo, ẹsin ko faaye gba wi pe ki awọn maa lọ ile oro tabi ṣe oro to le pa awọn maalu ọhun nibi kan ṣugbọn pe iwadii n lọ lọwọ lori ọrọ naa.

Nigba ti ikọ BBC n ba Kabiyesi sọrọ lori boya awọn maalu naa wọ ilẹ Ooṣa, Ọba alaye naa ni, wọn ko le sọ boya arinfẹsẹsi lo jẹ fun awọn maaluu naa ṣugbọn gbogbo rẹ yoo ni yanju.

Ọba Akadir wa ni ilu yoo ṣe pade pẹlu awọn agbaagba lati mọ ọna abayọ.

Kini o kọkọ ṣẹlẹ ṣaaju asiko yii?

Iṣẹlẹ kayeefi miran tun ṣẹ ni ipinlẹ Ondo lori pe àrá tun san pa maalu mẹjọ ni agbegbe Ikarẹ/ Akoko ni Ijọba ibilẹ Ila oorun ariwa Akoko ni ipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ ki ara maa san pa maalu kò ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ ni ipinlẹ Ondo.

Loṣu kan abọ sẹyin ni irufẹ iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Ijarẹ, ni Ijọba Ibilẹ Ifẹdọrẹ, ti maalu ti ko din ni mẹrindinlọgbọn si ku.

Iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ni ẹkan -ile, ti o jẹ pe ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni awọn Fulani darandaran bẹrẹ si ni ta oku ẹran naa fun ara ilu jẹ.

Bayii, Ijọba Ipinlẹ Ondo ti fofin de tita ẹran maaluu ni agbegbe naa titi ti iwadii yoo fi pari lori iṣẹlẹ naa.

Bayii, ẹka ti o n ri si ilera ara ilu ati awujọ ti fi panpẹ ọba mu awọn alapata ti o n ta eran ti ara pa yii fun ara ilu lẹyin ti wọn sun wọn ti wọn ṣeto rẹ daadaa.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ẹni ti o jẹ adari ẹka naa, Arabinrin Yemisi Adeniyi ati ojugba rẹ Ogbẹni Ojo Anthony sọ wi pe, awọn ti wọn mu yii ti wa ni ahamọ ofin.

Iroyin ni awọn maalu naa ku nigba ti wọn ṣeṣi rin lọ ori oke kan ti Oba ilu naa ti maa n lọ ṣe etutu ọlọdọọdun.

Wọn ti wa rọ awọn eniyan ilu lati yẹra fun rira ẹran maalu lasiko yii ni pataki, ẹran ti ara pa yii fun ilera ara wọn.

Bakan naa ni ẹni ti o jẹ alaga awọn alapata ni agbegbe naa, Arakunrin Kabiru Ismaila sọ pe, gbogbo ipa ni wọn yoo sa lati ri i pe iru ẹran bẹẹ ko wọ ọja.

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde