Abdurasheed Maina: Adájọ́ ní kí ọ̀gá àjọ tó rí sí owó ìfẹ̀yìntì tẹ́lẹ̀ sí wà látìmọ́lé

AbdulRasheed Maina

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdulsheed Maina

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ l'Abuja ti paṣẹ pe ki ọga ile isẹ to n risi owo awọn osisẹfẹyinti (pension) tẹlẹri, Abdurasheed Maina wa ni atimọle.

Adajọ Okon Abang paṣẹ yii ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC gbe e lọsi ile ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe oni oun ko jẹbi ẹsun onikoko mejila ti wọn fi kan an.

Adajọ Abang sun igbẹjọ naa si ọgbọn ọjọ, oṣu kẹwaa ati ọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla.

Ẹsun ikowojẹ, nini apo ikowo si ni banki tẹni kan o mọ ati iwa jibiti ni wọn fi kan Maina

EFCC gbé ọ̀gá owó ìfẹ̀yìntì tẹ́lẹ̀ lọ sÍ ilé ẹjọ́ fún ìwà ìbàjẹ́!

Ajo to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti gbe ọga ile isẹ to n risi owo awọn osisẹfẹyinti ( pension) tẹlẹri, Abdurasheed Maina ati ọmọ rẹ Fraisal lọ si ile ẹjọ giga to wa ni ilu Abuja.

Ẹ̀sun oniga mejila to niise pẹlu lilo owo ilu ni ponpo, lilo banki ayederu ati gbajuẹ ni EFCC fi kan Maina.

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Abdurasheed Maina àti ọmọ rẹ̀ Faisal ni wọ́n gbé ní ìlú Abuja lẹ́yìn tí wọ́n ti ń wá láti ọdún 2017 fún ẹ̀sùn lilu owo ilú ní póńpò.

Ọjọ Kejilelogun, Osu Kewaa ni Adajo Agba, Folasade Giwa-Ogunbanjo ti ile ẹjo giga pasẹ ki Maina fi dukia ile mẹtalelogun to ni silẹ.

Ile nlanla, adugbo ati ile isẹ Maina to wa ni Abuja, Kaduna, Borno ati Nasarawa wa lara awọn dukia naa ti wọn ri pe Maina lo nii.

Bakan naa ni ile ẹjọ pasẹ ki iwe iroyin ti orilẹede Naijiria fi lede pe ki Maina jọwọ gbogbo awọn dukia naa fun ijọba.

Ati wi pe ki ẹnikẹni ti ko ba fẹ jẹ ki ijọba gbẹsẹle awọn dukia naa jade pẹlu ẹri wi pe awọn ni wọn ni.

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé àwòrán,

EFCC ń gbé ọ̀gá Pension tẹ́lẹ̀ lọ sÍ ilÉ ẹjọ́ fún ìwà ìbàjẹ́!

Adajọ Okon Abang tile ẹjọ giga ni Abuja ni igbẹjọ naa ti n lọ bayii.

Wilson Uwujaren to jẹ agbẹnusọ EFCC ni o di dandan ki Maina ri aaye wi tẹnu rẹ lori awọn ẹsun wọnyii.

E wo bi ẹjọ Maina se bẹrẹ

2010 - Wọn fi jẹ alaga ajọ aare to n risi ọrọ ajẹmọnu ati owo osisẹfẹyinti

•2012 - Wọn fi ẹsun iwa ibajẹ kan an

•2013 - Wọn le ni isẹ ijọba apapọ

•2015 - EFCC sọ fun gbogbo eniyan pe awọn n wa Maina

•2015 - O sa pamọ (awọn eniyan ni Dubai lo salọ)

•2017 - Wọn fi je adele fun adari ile isẹ to n risi ọrọ abẹlẹ lorilẹede Naijiria

•2017 - Ọjọ Kẹtalelogun, Osu Kẹwa ni aare yo o nise

•2017 - Iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori rẹ - amọ awọn eniyan ni o lo sapamọ.