Olùkọ kan àti àwọn mẹ́ẹ̀dógún míràn ni wọn ti yẹgi fún ní Bangladesh

Oloogbe Nusrat

Oríṣun àwòrán, FAMILY HANGOUT

Àkọlé àwòrán,

Nusrat eni ti won da epo oyinbo si lara won si jo

Ijọba orilẹ-ede Bangladesh ti ran awọn mẹrindinlogun ọmọ orilẹ-ede naa ni ẹwọn gbere.

Ile ẹjọ da ẹwọn gbere fun awọn ọdaran naa lẹyin ti wọn dana sun ọmọ ile iwe kan ti orukọ rẹ n jẹ Nusrat Jahan.

Ọmọ ọdun mọkandinlogun ni Nusrat ti wọn kọlu lataari bi o ti fi ẹjọ olukọ agba ile iwe rẹ, Siraj Ud Doula, sun pe, o dẹnu ibalopọ kọ ohun.

Olukọ agba ile iwe naa ni iroyin ni ko fi ọmọbinrin naa lọrun silẹ.

Iroyin ni o tun dẹnukọ awọn ọmọbinrin meji miran ti o jẹ akẹkọọ bii Nusrat ki o to paa ni eyi to jẹ ki ile ẹjọ ni ki wọn yẹ igi fun un.

Nigba ti adajọ naa gbe idajọ rẹ kalẹ tan lori awọn ọdaran naa, ni lara wón ba bẹrẹ sini da omi loju yoloyolo ti wọn si n kigbe, ti awọn kan ni adajọ ko fun wọn ni idajọ ododo

Iku ọmọbinrin naa lo jẹ kayeefi si ọpọ awọn eniyan ti wọn si n beere idajọ ododo fun ọdọbinrin naa lori bi wọn ṣe ṣeku paa.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Awọn ọdaran ni ile ẹjọ

Bo tilẹ jẹ pe, inu awọn mọlẹbi rẹ dun si idajọ ile ẹjọ naa, amọ ọkan iya rẹ, Shirin Akhtar bajẹ pupọ ti o si n domi loju pe, oun ko le gbagbe rẹ ati iru irora ti ọmọ oun jẹ loju iku.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Awọn ẹbi Nusrat to kin in lẹyin lati fi ọrọ naa to Ọlọpaa leti ni wọn ti wa ni abẹ abo ajọ Ọlọpaa bayii fun aabo to daju gẹgẹ bi ẹgbọn rẹ, Muhmudul Hassan Noman ṣe sọ

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde