Yoruba Culture: Ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Yoruba Culture: Ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ojúbọ Ogun àti Eṣu ṣe pataki si eegun Danafojura - Danafojura

Aṣa ati iṣe Yoruba ṣe pataki si BBC Yoruba ki a to ṣẹṣẹ wa sọ ti iṣẹṣe ati igbagbọ awọn Baba nla wa.

Oriṣiriṣi eegun lo wa nilẹ Yoruba ṣugbọn ọtọ ni ti eegun Danafojura to n jade ni ilu Ogbomọsọ ni ipinlẹ Oyo ni guusu Naijiria.

Oloye Sunday Babatunde Olalere to n gbe eegun Danafojura lọwọ ṣalaye lẹkunrẹrẹ ohun to sọ akọwe ijọ di eegun l'Ogbomọṣọ.

Oyinlọla Olalere, iya Danafojura sọrọ lori itan eegun naa ati igbagbọ awọn eniyan nipa eegun naa pe o n gbọ adura awọn eniyan.

Ọpọlọpọ eewọ ati iṣẹse lo rọ mọ gbigbe eegun naa jade ni Ogbomọṣọ.

Yoruba ni ooṣa ti a ko ba fidi ẹ han ọmọde kii pẹ parun ni BBC ṣe lọ ṣe iwadii nipa eegun yii, kawọn ọdọ Yoruba le mọ pe agbara ṣi wa lọwọ awọn agba Oodua.

Epo pupa ati iyọ ṣe pataki lojubọ ki danafojura to jade.