Wọ́n ti ṣí ilé oúńjẹ ọgbọ̀n náírà (N30) lẹ́yìn tí mínísítà Nanono sọ pé oúńjẹ N30 le yó èèyàn

Ọ̀rọ̀ tí mínísítà ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsóké igbèríko sọ pé oúńjẹ N30 le yó èèyàn ní Kano bí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú.

Ǹjẹ́ lóòótọ́ èèyàn le rí oújnẹ́ ọgbọ̀n náírà rà ní Kano?
Àkọlé àwòrán,

Ǹjẹ́ lóòótọ́ èèyàn le rí oúnẹ́ ọgbọ̀n náírà rà ní Kano?

Àkọlé àwòrán,

Akọ̀ròyìn BBC tẹkọ̀létí lọ sí ilé oúńjẹ kan tí wọ́n sí lẹ́yìn tí mínísítà ètò ọ̀gbìn àti ìdàgbàsókè igbèríko, Sabo Nanono sọ pé èèyàn le jẹ oúnjé ọgbọ̀n náírà yó.

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n sọ ilé oújẹ náà ní Sabo Nanono, orúkọ mínísítà ètò ọ̀gbìn, wọ́n sì ''n ta oújẹ ọgbọ̀ náírà níbẹ̀

Àkọlé àwòrán,

Àwọn tí wọ́n dá ilé oúńjẹ náà sílẹ̀ sọ àwọn ti ń jẹ èrè lẹ́yìn tí àwọn dá ilé oúńjẹ náà sílẹ̀

Àkọlé àwòrán,

Èèyàn méjì ló dá ilé oúńjẹ náà sílẹ̀ ni eyi to ṣafihan pe ọrọ minista Mohammed Sabo Nanono pe ounjẹ ọgbọn naira wa ni Kano

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n kọọ́ sí iwájú ilé oúńjẹ náà pé wọ́n ń ta oújẹ ọgbọ̀ náírà níbẹ̀

Àkọlé àwòrán,

Nanono ni orúkọ tí wọ́n fún ilé oújẹ náà

Àkọlé àwòrán,

Àwọn kan nínú àwọn tí wọ́n jẹ oúńjẹ náà sọ pe àwọn yó, ṣùgbọ́n àwọn kan sọ pe wọn kò yó

Àkọlé àwòrán,

Àwọn kan sọ pé oúńjẹ náà ò dùn lénu.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn kan sọ pé oúńjẹ náà dùn lénu