High blood pressure: Lílo òògùn ẹ̀jẹ̀ ríru sùn lálẹ́ ló lè mú un ṣiṣẹ́ jùlọ

OOgun ẹjẹ rirun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

High blood pressure: Lílo òògùn ẹ̀jẹ̀ ríru sùn lálẹ́ ló lè mú un ṣiṣẹ́ jùlọ

Awọn ọnimọ sayẹnsi ti sọ wi pe lilo oogun ẹjẹ ruru lalẹ lo le mu oogun naa ṣiṣẹ lara ju.

Wọn ni igba to dara julọ lati loogun naa ni keeyan to sun lori ibusun rẹ lalẹ.

Iwadii fihan pe oogun yii maa n dena aarun rọpa-rọsẹ ati aarun ọkan t'eeyan ba loogun naa ko to sun lalẹ.

Awọn onimọ sayẹnsi ṣalaye pe aago to wa lara eeyan niiṣe pẹlu bi oogun ṣe maa n ṣiṣẹ lara eeyan.

Iwadii ti fihan pe o ni awọn akoko kan ti oogun le ṣiṣẹ daadaa lara eniyan ti o ba lo o.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eeyan bi ẹgbẹrun un mọkandinlogun ni wọn fi dan oogun yii wo ki wọn to sọ pe oogun ẹjẹ ruru yoo ṣiṣẹ julọ teeyan ba lo ko tun sun lalẹ.

Awọn onimọ oogun ṣalaye pe to ba ti di pe ẹjẹ ruru n lọ soke lai wa silẹ rara, o le ṣakoba fun ọkan eniyan.

Àkọlé fídíò,

Ogun flood: ọ̀ps àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde

Ọjọgbọn Ramon Hermida jẹ olori iṣẹ iwadii naa sọ pe awọn dokita le maa sọ fawọn to ba laarun ẹjẹ riru lati maa loogun wọn lalẹ ki wọn to sun bayii lẹyin ti iwadii ti fidi rẹ mulẹ.