Ofada Rice: kíni ẹ̀yin gbádùn nínú ìrẹsì ọ̀fadà?

Ofada Rice: kíni ẹ̀yin gbádùn nínú ìrẹsì ọ̀fadà?

Irẹsi ayamase dùn ju gbogbo irẹsi to ku lọ - Oluwọle Oluwatoyin

Irẹsi Ofada jẹ oriṣii irẹsi kan ti awọn iran Yoruba fẹran pupọ.

Lati agbegbe Ọfada ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti kọkọ gbin in ki o to di kari aye.

Irẹsi ọfada jẹ ti ibilẹ to maa n ṣara loore pupọ gẹgẹ bi wọn ṣe sọ lasiko ọdun ọfada to waye ni ipinlẹ Eko.

Gbenga Adeyinka, Oluwọle Oluwatoyin, Oluwatobi Ofada Boy, Abisọla Olusanya atawọn miran sọrọ nipa igbadun to kun inu irẹsi ọfada.

Ounjẹ jẹ ọkan lara awọn abuda adamọ to n fi aṣa iran tabi ẹya kan han bii Gaari àti ikọkọrẹ ni ti awọn Ijẹbu, Iyan ni ti Ijeṣa, lafun ni ti Ẹgba, Amala ni ti Ibadan.