Ẹ̀sùn àìmọ̀dí gbé Theophilous dọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìwé ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ méjì ló gbé jáde

Iloro ọgba ẹwọn kan.

Oríṣun àwòrán, The Nigeria Lawyers

Àkọlé àwòrán,

Ẹ̀sùn àìmọ̀dí gbé Theophilous dọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ìwé ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ méjì ló gbé jáde

Ṣe wọn ni ba o ku iṣe o tan.

Aṣamọ ọrọ yii gan an lo ṣakawe iroyin nipa Ọgbẹni Adeniyi Theophilous to gba iwe ẹri imọ ijinlẹ meji lasiko to fi wa lọgba ẹwọn.

Gẹgẹ bi ohun ti Ọgbẹni Adeniyi sọ fawọn akọroyin ni ilu Enugu, o ni n ṣe loun ronu si ọrọ awọn agba to ni iya meji ko gbọdọ jẹ okuugbẹ loun baa fi sare wa wọrọkọ fi ṣada.

O ni eyi lo mu oun lo anfani ibudo ikẹkọọ fasiti agbelegboye NOUN ti wọn da silẹ lọgba ẹwọn ilu Enugu lati fi kẹkọọ gboye ijinlẹ.

O ni iyalẹnu lo kọkọ jẹ fun ọpọ awọn ẹlẹwọn nibẹ nitori ko sẹni to gbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn gbe fasiti wa sọgba ẹwọn.

Bi o tilẹ jẹ pe ọgbẹni Adeniyi kọ ni ẹlẹwọn akọkọ ti yoo kẹkọ gba oye ijinlẹ lọgba ẹwọn ṣugbọn ko fẹẹ si eyi to tii gba meji nibẹ ṣaaju rẹ.

Ṣe wọn ni inu ẹni kii dun ka paa mọra, Ọga wọda ni ipinlẹ Ẹnugu, Ọgbẹni Mustapha Attah ti ko lee pa idunnu rẹ mọra kan sara sawọn ẹlẹwọn to n lo asiko wọn ni ile ọgbọn naa lati fi tun igbesi aye wọn ṣe.

Attah ni paapaa julọ nipa itẹsiwaju ẹkọ wọn pẹlu ileri pe nibayii, ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹ-ede Naijiria ni yoo maa gbọ ilaji bukata owo ileewe ẹlẹwọn yoowu to ba fẹ kẹkọ lasiko to ba wa lẹwọn.

Ọgbẹni Adeniyi ni ọdun mẹsan an sẹyin ni wọn taare oun lọ sọgba ẹwọn ni ilu Ẹnugu pe ki oun wa nibẹ titi di igba ti wọn yoo fi yanju ẹjọ lori ẹsun ti wọn fi kan oun nipa wahala ija laarin ileto si ileto kan to waye nigba naa.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Adeniyi ni lootọ, wahala pe oun wa lẹwọn to domi tutu si ọkan oun ṣugbọn pẹlu ifaraẹnijin ati ilakaka gbogbo to yẹ oun bori nigbẹyin.

O fi kun un pe ninu awọn ẹlẹwọn marundinlọgbọn to forukọ silẹ ni ileewe naa lọdun 2015, oun nikan lo pari.

Ẹkọ nipa ipẹtusaawọ lo kọ to si yege pẹlu ami keji nileewe giga fasiti, iyẹn second class upper (2.1)

Lọjọ karun un, oṣu kẹwaa, ọdun 2015 ni wọn daa silẹ pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an lẹyin to lo ọdun marun un ati oṣu mẹfa lọgba ẹwọn to n reti idajọ ile ẹjọ.

Àkọlé fídíò,

Ofada Rice: kíni ẹ̀yin gbádùn nínú ìrẹsì ọ̀fadà?