Ondo Kidnap: Àwọn ajínigbé tú adájọ́ kóòtù àpapọ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ márùn ún lákàtà wọn

Aworan awọn ohun elo iṣedajọ

Oríṣun àwòrán, The Nigeria Lawyers

Onidajọ Abdu Dogo ti awọn ajinigbe kan ji gbe lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii ti gba itusilẹ oGéńdé agbébọn jí adájọ́ gbé lọ ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Ni agogo meji oru ọjọ Satide tii ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa ni wọn tuu silẹ lẹyin ti awọn ajinigbe naa jii gbe lasiko to fi n rin irinajo bọ lati ilu Abuja lọ si ilu Akurẹ.

Awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko damọ lo ji Adajọ naa gbe ti wọn ni wọn n beere fun aadọta milionu owo itanran.

Ko tii si ẹni lee sọ ohun to ṣẹlẹ ti wọn fi tuu silẹ bayii.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni kete ti iroyin ijinigbe rẹ kan sita ni Ọga agba ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, ti dari ikọ ọtẹlẹmuyẹ eleyi ti ọga ọlọpaa, Abba Kyari ko sodi lati tete ṣawari Onidajọ Abdu Dogo ni kiakia.

Adajọ ileẹjọ giga apapọ orilẹ-ede Naijiria ni ilu Akurẹ ni Onidajọ Dogo.

A o maa mu alaye kikun si wa ni kete ti a ba ti mọ bo ṣe gba itusilẹ.

Oríṣun àwòrán, The Nigeria Lawyers