Pius Adesanmi: Òní ni ẹ̀bí akọni Pius Adesanmi n ṣètò ìkẹyìn fún ogbontarigi náà

Image copyright @Pius
Àkọlé àwòrán Ilẹ n jẹ eeyan!

Ọsan oni, ni deede aago mejila ni ẹbi ara ati ọrẹ oloogbe Pius Adesanmi fẹ ṣeto isinku rẹ ni Ottawa, Ontario ni orilẹ-ede Canada.

Oloogbe Pius Adesanmi ni ogbontarigi olukọ ati onkọwe ọmọ Naijiria to fi Canada ṣe ibujoke to dollogbe nibi ijamba ọkọ ofurufu Ethiopia to waye loṣu kẹta ọdun yii.

Ojọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun 2019 lo wa ninu awọn ẹmi to sọnu nigba ti ijamba ọkọ ofurufu yii ṣẹlẹ.

O n lọ irinajo lati laarin Adis Ababa ati Nairobi nibi ti eniyan mẹtadinlogojo ti doloogbe.

Ojọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keji, ọdun 1972 ni a bi oloogbe Pius Adesanmi.

O jẹ ọmọkunrin kan ṣoṣo ti iya rẹ bi laarin ọmọ mẹta, oun naa tun ni abigbeyin iya wọn.

Okan pataki lara awọn iwe to kọ ki ọlọjọ to de ni Naija No Dey Carry Last, A 2015 collection of satirical essays.

Ebi, ara ati awọn ojulumọ ni gbogbo wọn n ṣe idaro ẹni rere to lọ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPius Adesanmi ní Wole Soyinka ìran yìí - ọmọ Naijiríà

Diẹ lara awọn ibi ti Pius ti ṣiṣẹ ni fasiti Pennsylvania ni America, French Institute for Research in Africa ati ti South Africa ko to wa di ọjọgbọn ni fasiti Carleton ni Ottawa, ni orilẹ-ede Canada.

Image copyright @others
Àkọlé àwòrán Oni ni wọn n ṣe ẹyẹ ikẹyin fun akọni

Ọpọ igba ni Pius Adesanmi maa n sọrọ nipa Naijiria tuntun nigba aye rẹ.

O maa n sọrọ lori awọn iṣoro to n koju awọn eniyan Naijiria, awọn wahala to de ba eto ọrọ aje ati igbe aye alaafia Naijiria nigba aye rẹ pupọ.

Capital Funeral Home and Cemetary ni wọn ti maa sin ọjọgbọn ọmọ ipinlẹ Kogi ni aarin gbungbun Naijiria yii si lọsan oni.

Tẹbi-tara tojulumọ lo maa pade lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun un ni Canada.

Itedo-Ijowa ni Agbegbe Isanlu, nijọba ibilẹ Ila oorun Yagba ni a ti bi Pius nipinlẹ Kogi.

Lasiko ti a bii lọdun 1972, ijọba ibilẹ Isanlu ṣi wa labẹ ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti yọ apa kan ipinlẹ Ondo.

Orọ igbẹyin ti Pius Adesanmi fi soju opo Facebook rẹ fi igbagbọ rẹ ninu Oluwa han pe:

Image copyright @Pius
Àkọlé àwòrán afi bii pe akọni n dagbere .....
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionYoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde