Russia Shooting: Ọmọ ogun mẹjọ ni ilẹ Russia ni wọn ti ríkú òjiji he tí méjì míràn si farapa.

Russia
Àkọlé àwòrán,

Aworan ile Russia ti ọmọ ogun ilẹ ti da ibọn bo awọn akẹgbẹ rẹ

Ọmọ ogun ilẹ Russia kan ti ṣeku pa ojugba rẹ mẹjọ ti o si ṣe meji miran leṣe ninu ipagọ awọn ọmọ ogun ilẹ naa.

Awọn alaṣẹ ologun ilẹ naa wi pe o ṣeeṣe ko jẹ wi pe, arakunrin naa, Ramil Shamsutdinov, ni aarun ọpọlọ, ti wọn si ti fi si ihamọ.

Iṣẹlẹ yii lo waye ni aṣalẹ ọjọ Eti ni ibudo ipagọ ni abule Gorny, ti ko jinna si Chita.

Awọn alaṣẹ naa ni iwadii si ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Kini o ṣẹlẹ gangan nibudo ipagọ awọn ọmọ ogun?

Iṣẹlẹ yii waye ni nkan bii aago mọkanla kọja iṣẹju mẹẹdogun alẹ ọjọ Eti gẹgẹ bi ohun ti igbimọ iwadii ilẹ Russia sọ.

Ẹka ti o n ri si eto aabo ti sọ ṣaaju pe, arakunrin naa yin ibọn naa ni kete ti awọn ọmọ ogun mura ogun.

Ọgbẹni Shamsutdinov pa oṣiṣẹ meji pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ jẹ ọmọ ogun mẹfa.

Ẹni ti o jẹ igbakeji Minisita fun eto aabo ni ilẹ naa, Andrey Kartapolov yoo ṣaaju ikọ ti yoo ṣe iwadii ọrọ naa.

O di dandan fawọn ọdọkunrin ti ọjọ ori wọn wa laarin ẹni ọdun mejidinlogun si mẹtadinlọgbọn lati darapọ mọ awọn ọmọ ogun ninu alakalẹ eto ilẹ Russia.

Ti wọn yoo si wa fun iṣẹ afi-ara-ẹni-jin bii isinru ilu ọlọdun kan ṣugbọn ti anfaani si n bẹ fẹni to ba fẹ sun siwaju si i.

Ni awọn asiko kan sẹyin, ni awọn ajafẹtọ-ọmọniyan maa n tabuku ijọba ilẹ naa lori bi wọn ṣe n dari awọn ologun lọna aitọ ṣugbọn ti wọn ti wa ni ologun ni kalẹ bayii.