Ogun Accident: Èèyàn mẹ́wàá kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ lánà mọ́rosẹ̀ Ṣagamu sí Ijebu Ode

Ijamba ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, @AJISCO30

O kere tan eeyan mẹwaa lo d'oloogbe ninu ijamba ọkọ meji to ṣelẹ lọjọ Satide loju ọna mọrosẹ ilu Ṣagamu si Ijebu Ode.

Ọga agba fun ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC ti ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Clement Oladele ṣalaye pe, eeyan mẹrindinlogun lori ko yọ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ọgbẹni Oladele ṣalaye pe, awọn ole ti wọn n ṣọṣẹ loju ọna naa lo ṣokunfa ijamba ọkọ akọkọ ninu eyi ti eeyan meji ti ku.

Ọga ajọ FRSC fikun ọrọ pe, awakọ kan lo ṣadeedee lọri lẹyin to kan awọn ole loju ọna lojiji, eleyi to mu wọn kọlu ọkọ akẹru nla to n bọ.

Oríṣun àwòrán, @AJISCO30

Ọgbẹni Oladele ṣalaye pe, ijamba ọkọ keji waye nigba ti ọkọ ajagbe agbepo ati ọkọ bọọsi akero to n bọ lati ilu Okitipupa kọlu ara wọn.

Ajọ FRSC ni ile iwosan ijọba to wa niluu Ijẹbu ode ni wọn ko awọn to farapa ninu ijamba ọkọ naa lọ.

Bakan naa ni won ko oku awọn to ku lọ si ile igbokusi nile iwosan yii kan naa.