Lady Jibowu: Ẹni ọdún 95 ló dágbére fáyé pé ó dìgbóṣe

Lady Deborah Jibowu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ekiti State Government

Iku n pani, ilẹ n jẹyan, gbogbo ilẹ Yoruba ati orilẹede Naijiria n ṣedaro mama Ọlọla Deborah Opeyemi Jibowu to jẹ obinrin akọkọ ni Naijiria, to kawe gboye akọkọ ninu imọ sayẹnsi.

Opeyemi Jibowu jẹ Ọlọrun nipe lẹni ọdun marun din lọgọrun un, ti aya Gomina ipinlẹ Ekiti, Bisi Fayemi naa si ti ranṣẹ ibanikẹdun si ẹbi oloogbe Fasanmade niluu Ido-Ile nipinlẹ Ekiti.

Ta ni mama Lady Deborah Opeyemi Jibowu gan an?

  • Ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 1924 ni wọn bi Lady Deborah Opeyemi Jibowu si idile Oloye ati alufa, Olujudo ti Iddo, Rev Fasanmade
  • Ile iwe C.M.S Day Schools niluu Eko lo kọkọ lọ, ṣugbọn o darapọ mọ ile iwe girama Kudeti Girls School niluu Ibadan lọdun 1934 nipasẹ ologbe Biṣọbu Jones
  • Mama Deborah Opeyemi tẹsiwaju ẹkọ rẹ nile iwe girama C.M.S. Girls School niluu Eko nibi to ti jade lọdun 1941
  • O bẹrẹ iṣẹ olukọ nile iwe C.M.S. Girls School ati Queens College lẹyin to pari ẹkọ rẹ
  • Mama Deborah Jibowu tun kẹkọọ nile iwe United Missionary College niluu Ibadan lọdun 1942
  • O kẹkọ gboye ninu imọ-ijinlẹ sayẹnsi ni fasiti ilu Manchester lati ọdun 1944 si 1948 nilẹ Gẹeṣi.

Idile Mama Deborah Opeyemi Jibowu

Mama Deborah Opeyemi Jibowu ṣe igbeyawo pẹlu Olumuyiwa Jibowu lọjọ kẹjọ oṣu keje ọdun 1950.

Ọlọrun fi ọmọkunrin meji ati ọmọbinrin ta idile naa lọrẹ.

Mama Deborah Jibowu kopa ninu eto oṣelu

Mama Deborah Jibowu jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ igbimọ ajọ to n ri si ijọba ibilẹ laarin ti ijọba iwọ oorun ni Naijiria yan larrin ọdun 1959 si ọdun 1971.

O tun jẹ kọmiṣọna ajọ to n ri si eto ikaniyan(National Population Census) lọdun 1981 si 1983.

Ilẹ Gẹeṣi fi oye 'Member of the British Empire (MBE)' da a lọla lọdun 1962, lẹyin naa ni orilẹede Naijiria fun un ni oye Officer of the Order of the Niger (OON) lọdun 1965.

Mama Deborah Opeyemi Jibowu tun jẹ oye mama isalẹ fasiti ilu Calabar lọdun 1993 si ọdun 1997.