Rehab Homes: Ọmọdébìnrin kan sọ bí òun ṣe di ẹ̀rọ ìbálòpọ̀ níbùdó aláìgbọràn

Awọn eeyan to wa nibudo awọn ọmọ alaigbọran

Oríṣun àwòrán, @nigeria_true

Obinrin kan, ẹni ogun ọdun ti ori ko yọ nile awọn ọmọ alaigbọran to wa nilu Ilọrin, Laide Arikewuyọ, ti salaye ohun ti oju rẹ ri lasiko to wa nile naa.

Laide, to jẹ ọkan lara awọn ọmọbinrin mejidinlaadọfa ti wọn ri idande gba kuro nile ọmọ alaigbọran naa sọ pe awọn ọmọ ati ibatan oludasilẹ ile ọmọ alaigbọran naa, lo ti sọ ohun di ẹrọ ibanilopọ, ti wọn si n sun ti oun bo se wu wọn.

Nigba to n sọ ohun ti oju rẹ ri ninu ile naa fawọn akọroyin salaye pe ẹni ta gboju okun le, ko jọ ẹni agba lọrọ awọn eeyan ti wọn ni ki wọn maa se akoso ile alaigbọran naa, nitori iwa aidaa nidi ibalopọ lọna ti ko tọ gan lawọn naa n hu.

O fikun pe nigba ti awọn obi oun ko lee setọju oun bo se yẹ ni oun sa kuro nile, ni kete ti wọn si ri oun pada, lawọn obi oun mu ohun lọ sile alaigbọran naa, ti Mallam Abdulraheem Owotutu da silẹ.

Oríṣun àwòrán, @nigeria_true

"Mo ti n gbe nibudo naa lati ọdun marun sẹyin, mo si maa n ni ibalopọ loore koore pẹlu awọn ọmọ ati mọlẹbi Mallam Owotutu, ko si din ni marun ninu awọn alakoso to n setọju ibudo naa, to ti ba mi ni ajọsepọ."

Laide fikun pe oun ranti pe oun loyun ni ẹẹmẹta ọtọọtọ, amọ wọn maa n fun oun ni oogun ti ko ni jẹ ki oyun naa duro lara oun.

Nigba ti oun naa n salaye ohun to gbe de ile ọmọ alaigbọran naa, Tọpẹ Collins Owonifaari salaye pe awọn eeyan kan ti oun ko mọ lo gbe nilu Eko, ti oun si ba ara oun nibudo to dọti naa, nibiti wọn ko awọn papọ si bii ẹran.

Tọpẹ ni ọjọ mẹrin pere ni oun ti lo nibudo naa, ki ori to ba oun se ti awọn ọlọpa fi wa fọ ibudo ọhun.

Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin laipẹ yii pe lọjọbọ to kọja nileesẹ ọlọpa ipinlẹ Kwara safihan awọn ọmọge, ọkunrin ati ọmọde, ti wọn tu silẹ nile ọmọ alaigbọran kan to wa ladugbo Gaa Odota nilu Ilọrin.