Prepaid Meter: Ọmọ Nàíjíríà figbe ta pé owó iná táwọn ń san ju iná táwọn ń lò lọ

Mítà ìgbàlódé Prepaid

Oríṣun àwòrán, Ikeja Electric

Ọrọ ina ọba to n se segesege lorilẹede Naijiria ati bi ileesẹ amunawa se n beere owo ina ti wọn ko pese ti n ru awọn ọmọ Naijiria laya soke bayii.

Se ni oju opo Twitter n gbona lala, tawọn ọmọ Naijiria si ti n fohun sọkan pe ti ileesẹ to n pese ina ọba lorilẹede yii ko ba pese ẹrọ igbalode to n ka iye ina taa ba lo, taa mọ si Prepaid Meter, awọn ko ni san owo ina mọ.

Awọn ọmọ Naijiria, ti wọn se ipinnu bẹẹ loju opo Twitter wọn, labẹ akori #NoMeterNoPayment, wa salaye lẹkunrẹrẹ nipa ọpọ ohun ti oju wọn n ri lọwọ ajọ to n pese ina ọba, pẹlu bi wọn se n beere owo gege lai pese ina ọba to duro re.

Oríṣun àwòrán, Ikeja Electric

Olaniyi Alesinloye, @alesolas lasiko to n da si ọrọ naa ni ojuse awọn ọmọ Naijiria ni lati sanwo ina ọba ti wọn ba lo, ojuse awọn ileesẹ amunawa naa si ni lati si iye owo ina ti araalu kọọkan ba lo, sugbọn ọna to dara julọ lati se eleyi ni ki wọn fun araalu ni ẹrọ igbalode Prepaid meter.

June16 @jcallisto n tiẹ ni inu ile oni yara meji ni oun n gbe. Oun ni giloobu mẹjọ, ẹrọ amomitutu kan, faanu meji laisi tẹlifisan abi awọn ohun eelo amadẹrun miran, sibẹ, ileesẹ amunawa n beere ẹgbẹrun mẹrin si meje lọwọ oun losoosu.

Amọ alabagbele oun to ni awọn ohun eelo igbalode ninu ile, to fi ms ẹrọ ifọsọ n san ẹgbẹrun meji lori ẹrọ igbalode prepaid meter rẹ, nitori naa, laisi Prepaid meter, oun ko ni sanwo ina.

Sultan n tiẹ, @the Gr8t ni awọn osisẹ amunawa yii n gbe iwe owo ina gọbọi wa fun araalu, ki awọn baa lee fun wọn ni owo abẹtẹlẹ ẹgbẹrun kan si meji naira, ti wọn yoo si tun pada wa lẹyin ọsẹ meji lati wa gba owo ibi naa.

Idi si ree ti oun se n faramọ pe laisi Prepaid meter, owo ina ko ni jẹ sisan.

Collins O @OkoroCollins lero tiẹ ni iwa jibiti to tii ga julọ lorilẹede Naijiria ni owo ina sisan, o ni wọn maa n mu awsn ni tipa lati san owo ina ti wọn ko lo, lẹyin eyi ni eeyan kan yoo wa ni oun n gbogun tiwa ajẹbanu.

Ẹ jọwọ, iru iwa ajẹbanu wo lo tun ju eyi lọ?

Ojnimi @Ojnimi sọ loju opo rẹ pe iwa ijanilole to buru jai ni eyi. Ẹ wo ileesẹ amunawa to wa ni Ikeja to ni ki n san owo ina ẹgbẹrun mẹtadinlogun losu to kọja, amọ losu yii, ẹgbẹrun lọna mejidinlogun lo tun ni ki n san.

Ki lo de na, se a pa baba yin ni? Buhari ati Osinbajo, ẹ wa nkan se lori owo ina gọbọi ko to di pe a bẹrẹ si ni fi ẹhonu han.

Bakan si ni ọpọ ọmọ Naijiria koro oju si iwe owo ina gege ti ileesẹ amunawa ni Naijiria fisita, eyi ti wọn n pariwo pe ko ba awọn lara mu.