Abu Bakr al-Baghdad: Orílẹ̀èdè Amẹrika náà ti kọlu aṣaájú ẹgbẹ́ ISIS

Abu Bakr al-Baghdad

Oríṣun àwòrán, AFP

Awọn ologun orilẹede Amẹrika ti kọlu asaaju ẹgbẹ adunkooko mọni ISIS, Abu Bakr al-Baghdad.

Aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump lasiko to n soro pataki nipa isẹlẹ naa ni Abu Bakr al-Baghdad ku bi aja, ti o si n pariwo pe oun ko fẹ ku.

Aarẹ Trump sọ wi pe ko ku bi ajagun tabi akinkanju, nitori naa oun fẹ ki awọn to n tẹle mọ wi pe ọlẹ to n gbọn jinijini ni Abu Bakr al-Baghdad ki o to ku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọpọ igba ni iroyin ti n ja tẹlẹ pe wọn ti pa agbesunmọmi ọhun, ti awọn oju ewe iroyin to n tọkasi awọn alasẹ ti ko darukọ ni ikọ ọmọ ogun Amẹrika dojukọ asaaju ikọ adunkokomọni naa lasiko ikọlu to waye lagbegbe Idlib, lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Syria.

Oludari ikọ ologun Syrian Democratic Forces (SDF) ti ẹya Kurd n dari, Mazloum Abdi salaye pe "ikọlu manigbagbe to jẹ aseyọri" lo waye lati ipasẹ "isẹ ọpọlọ ajumọse" pẹlu orilẹede Amẹrika.

Ta ni Abu Bakr al-Baghdad?

Abu Bakr al-Baghdad nii se asaaju ẹgbẹ agbesunmọmi IS, ẹni ti wọn se apejuwe gẹgẹ bii ẹni ti wọn n wa julọ lagbaye.

Losu Kẹwa ọdun 2011, orilẹede Amẹrika kede rẹ bii 'Adunkokomọni' to si kede miliọnu mẹwa dọla bii ẹbun owo fun ẹnikẹni to ba pese iroyin lori bi wọn se lee mu tabi paa. Owo yi si ni wọn tun safikun rẹ si miliọnu mẹẹdọgbọn dọla lọdun 2017.

Ọmọ ilu Baghdad naa lo gbajumọ fun sise ọpọ ikọlu to n mu ẹmi eeyan lọ.

Ilu Samarra, lẹkun ariwa Baghdad ni wọn ti bi lọdun 1971, orukọ rẹ gangan si ni Ibrahim Awad al-Badri.

Iroyin kan ni ojisẹ Ọlọrun ni ninu mọsalasi kan lasiko ti orilẹede Amẹrika kọlu Iraq lọdun 2003, sugbọn awọn eeyan miran gbagbọ pe o ti di ajijagbara fun ẹsin Islam lasiko ti Saddam Hussein, asaaju orilẹede Iraq nigbakan ri, wa lori aleefa.

Awọn miran ni o ti di agbesunmọmi lasiko ti wọn mu nigbekun nibudo Camp Bucca, tii se ibudo kan to jẹ tilẹ Amẹrika nibiti wọn n fi awọn asaaju ikọ agbesunmọmi Al-Qaeda pamọ si.

Abu Bakr al-Baghdad lo wa di asaaju ikọ Al-Qaeda lorilẹede Iraq lọdun 2010, to si jẹ ọkan lara awọn ikọ agbesunmọmi to darapọ lati se agbekalẹ ikọ adunkooko mọni IS, to si di ilumọọka lasiko ti wọn fẹ darapọ mọ ẹgbẹ ọlọtẹ al-Nusra ti orilẹede Syria.