Ambode: Ilé aṣòfin Eko ní kí gómìnà àná wá wí tẹnu rẹ̀ lórí owó ọkọ̀ BRT

Ambode niwaju ile a#sofin eko

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti kọwe pe gomina ana ni ipinlẹ naa, Akinwunmi Ambọde pe ko yọju niwaju igbimọ ile naa, to n ṣewadi awọn ohun kan to ṣokunkun lasiko iṣejọba rẹ.

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ni Ọjọru ni wọn fun Ambọde lati farahan, ki o lee wa ṣe afọmọ ọrọ nipa awọn inawo kan to waye ni saa iṣejọba rẹ.

Bi o tilẹ jẹ wi pe o ti ṣe diẹ ti iroyin lori pipe Ambọde ti n waye nile asofin ipinlẹ Eko, ṣugbọn ọrọ naa ṣẹṣẹ ja gbangba ni pẹlu bi ile ṣe fi iwe ipe rẹ soju ewe iwe iroyin lọjọ abamẹta.

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Olori ile aṣofin ipinlẹ Eko, Mudaṣiru Ọbada gbe igbimọ ẹlẹni mẹrindinlogun kan kalẹ, lati tan ina wo eto inawo ra ọkọ akero nlanla BRT atawọn akanṣe iṣẹ miran.

Awọn akanse isẹ naa lo da lori ileeṣẹ to n fọ irẹsi ni Imọta, Imota Rice mill, ọna olobiripo to wa l'Oṣodi ati ina oju popo LED-UK streetlight project ti wọn ni gomina Ambọde ṣe nigba to wa lori aleefa.

Bakan naa ni olori ile aṣofin ni Ambọde ko gba ifọwọsi ile aṣofin ọhun ki o to rawọ le rira awọn ọkọ nla akero BRT okoolelẹgbẹrin to ra.