Yọmi Fabiyi: Ọ̀pọ̀ òṣèré ló ń ṣe ìlara akẹgbẹ́ wọn lórí ayélujára èyí tó ń fa ìjà

Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Yomi Fabiyi

Ọpọlọpọ awọn oṣere lo n lo oju opo ayelujara lati ṣe ibajẹ awọn oṣere ẹgbẹ wọn, asiko si ti to fun awọn alẹnulọrọ nileeṣẹ amuludun, paapaa ere tiata, lati wa nnkan ṣe si ọrọ yii.

Yọmi Fabiyi, tii se ilumọọka osere tiata kan lo woye ọrọ yii, lasiko to kopa lori eto kan ni ileeṣẹ BBC News Yoruba, pẹlu afikun pe, ọpọ awọn oṣere lo maa n ṣe koriya fun awọn ololufẹ wọn lati tako oṣere ẹgbẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti o n pẹ ọrọ sọ lori ija to wa laarin Liz Anjọrin ati Toyin Abraham, Yọmi Fabiyi ni abosi ati aifẹ dojukọ otitọ ohun gan to fa wahala laarin awọn oṣere tiata mejeeji yii, lo jẹ ki ija naa wa nilẹ fun ọjọ pipẹ.

Oríṣun àwòrán, Yomi fabiyi

O ni ọpọlọpọ iwa ilara lo n farahan laarin awọn oṣere tiata eleyi ti o ti n ran awọn ololufẹ wọn.

O ni ika ti wọn ṣe fun Lizzy Anjọrin lo mu ko pariwo sita, ti oun naa si ja pada lori ọrọ to waye laarin oun ati Toyin Abraham.

Gẹgẹ bii ọrọ rẹ, n ṣe ni Toyin Abraham maa n lo ayederu oju ayelujara pẹlawọn ololufẹ rẹ kan, lati maa sọ ọrọ buruku si awọn akẹẹgbẹ rẹ ati pe, eyi to ṣe si Lizzy Anjorin lo faa ti Lizzy naa fi fesi pẹlu rẹ.

Yomi Fabiyi ni igbesẹ ti ọpọ n gbe lati pari ija laarin Lizzy Anjọrin ati Toyin Abraham lai ba awọn mejeeji wi nitori iwa ibajẹ ti wọn hu, ko lee dẹkun atunṣe irufẹ iwa bẹẹ lọjọ iwaju.

Oríṣun àwòrán, yomi fabiyi

O ni o yẹ kawọn araalu tubọ yẹ ọrọ naa wo finifini, to fi jẹ pe Toyin nikan ni awọn eeyan bii Funkẹ Akindele, Bimbọ Ọṣin, Fathia Williams ba ni gbun-gbun-gbun lai jẹ pe, oun yii naa nikan lo wa nileeṣẹ ere tiata Yoruba lorilẹede Naijiria.

O ni ka ni Toyin Abraham gbe Liz Anjọrin lọ sile ẹjọ naa, ko si bi ko ṣe ni jẹbi bọ nibẹ nitori ẹri iwa ibajẹ rẹ wa nilẹ.

Bakan naa lo tun sọrọ lori idojukọ ti gbajugbaja adẹrinpoṣonu osere tita Yoruba, Babatunde Omidina, tọpọ eeyan mọ si Baba Suwe, ni pẹlu ajọ to n gbogun ti ogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA.

Yọmi Fabiyi ni didakẹ ti ẹgbẹ oṣere tiata Yoruba dakẹ lasiko idojukọ naa ku diẹ kaa to, ko si ṣapẹrẹ ẹgbẹ naa gẹgẹ bii eyi to karamasiki igbayegbadun awọn oṣere tiata.