Ẹ wo ǹkan tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa Tiwa Savage àti Wizkid tó fẹnu ko ara wọn

Tiwa Savage ati Wizkid

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Òri ẹ̀rọ ayélujara ń gbóná jainjain lẹ́yìn tí fídíò kan jáde níbi tí Tiwa Savage àti Wizkid ti ń fẹnu ko ara wọn.

Ọpọ ololufe gbajugbaja awọn olorin takasufe ọmọ Naijiria Tiwa Savage ati Wizkid lo n fi ero wọn han lori ẹrọ ayelujara lẹyin ti wọn ri fidio kan ninu eyi ti awọn akọrin mejeeji naa ti f'ẹnu ko ara wọn lẹnu.

L'oju opo Twitter ni awọn eniayn ti n bere pe ki lo wa laarin awọn mejeeji, se ololufẹ ni wọn ni tabi ọrẹ lasan?

Bi awọn kan se n bu ẹnu atẹ lu bi awọn mejeeji se fi ẹnu ko ara wọn , ni awọn miran sọ wi pe ifẹ to wa laarin awọn mejeeji wu awọn.

Amọ, ni ọpọ igba ni Tiwa savage ati Wizkid ma n sọ wi pe ọrẹ timọtimọ ni awọn mejeeji.