Tunde Bakare: Èbù ìkà táwọn kan ń gbìn, ọmọ wọn á jẹ níbẹ̀

Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Facebook/Tunde Bakare

Faabada! Ẹ ko nii lọ lai pọ ohun ti ẹ ji! Pasitọ ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare lo sọrọ yii nigba to n waasu lọjọ Aiku.

Pasitọ Bakare to ṣe agbatẹru ẹgbẹ Save Nigeria Group sọrọ lowelowe ninu iwaasu ọjọ Aiku ninu ijọ rẹ.

Bakare woye pe, ''aimọkan lo mu awọn eeyan maa ki ole to ji nnkan wọn ni mẹsan an mẹwaa, wọn ni oninure ni ati wi pe o lawọ.''

Alufa Bakare to figba kan dije pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bi igbakeji aarẹ sọ pe, aṣiwere ni ẹnikẹni to ba le sọ pe ẹnikan ti ji owo ilu ni tootọ ṣugbọn oninure lẹni naa.

Pasitọ ijọ Latter Rain ni idi niyii ti oju titi fi kun fun koto ati gegele nitori wọn ti ko owo to yẹ ki wọn fi ṣatunṣe ọna jẹ, lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si ijọba awarawa.

Pasitọ Bakare ni ''niṣe ni wọn n kọle kiri bi ẹyẹ, wọn nile ni Bourdillon, bẹẹ ni wọn nile kaakiri nitori wọn ti k'owo ilu jẹ.''

O fikun ọrọ rẹ pe, ebu ika ni wọn n gbin, o si di dandan ki ọmọ wọn o jẹ nibẹ.

Bakare ni o ṣeni laanu wi pe awọn ole ti wọn ti ji owo ilu lawọn ọmọ Naijiria n gboṣuba fun, nigba ti wọn n tako awọn to n ja fun wọn.

O ni ijọba ko tii ṣe ohun to yẹ ko ṣe lori ẹkun omi to n yọ ilu Eko lẹnu lọdọọdun.

Pasitọ Latter Rain Assembly tun sọrọ lowelowe lori ibo aarẹ ọdun 2023, o ni ''ẹ ku oriire o ẹyin ti ẹ fẹ dije fun ipo aarẹ, amọ ko lee ṣeeṣe ki ẹ ji ohun to jẹ ti gbogbo ọmọ Naijiria.''

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti gbe Tunde Bakare ri lọdun 2002 lori ẹsun wi pe iwaasu ta ba ijọba to wa lode.