ASUU: Adari ilé aṣòfin àgbà l'Abuja ṣèpàdé pẹ̀lú wọn lórí ááwọ̀ nípa IPPIS

Iwaju Fasiti Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter/ASUU

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni Naijiria, ASUU yoo ṣepade pẹlu awọn adari ile aṣofin agba mejeeji l'Abuja lọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa lori ilana igbalode ti ijọba fi n san owo oṣu, IPPIS.

Ẹ o ranti pe Aarẹ Muhammadu Buhari paṣẹ ninu aba eto iṣuna ọdun 2020 pe, gbogbo oṣiṣẹ ijọba gbọdọ forukọ silẹ fun ilana IPPIS lati le gbogun ti iwa ibajẹ ati lati jẹki ijọba apapọ lanfaani lati fowo pamọ.

Amọ, ajọ ASUU tako igbesẹ Aarẹ yii, wọn ni igbesẹ naa lodi sofin to fun ajọ ASUU lagbara lati maa ṣakoso ara rẹ.

Ajọ ASUU tiẹ tun sọ pe, lai sanwo fawọn olukọ fasiti, awọn ko ni ṣiṣẹ, lẹyin ti ijọba ni awọn oṣiṣẹ ti ko ba forukọ silẹ fun ilana IPPIS ko ni gbowo oṣu.

Ẹwẹ, oluṣiro owo apapọ ni Naijiria, Alhaji Ahmed Idris ni bi ajọ ASUU ṣe tako ilana IPPIS fihan pe ajọ naa fọwọ si iwa ajẹbanu.

Bakan naa, minisita eto inawo, Zainab Ahmed sọ pe gbogbo ẹka ijọba lo yẹ ko faramọ ilana IPPIS.

Oríṣun àwòrán, @favloadedblog

Amọ, aarẹ ajọ ASUU, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi ṣalaye pe ASUU ṣetan lati jiroro pẹlu ile aṣofin agba l'Abuja lori ọrọ IPPIS, atawọn ọrọ miiran to ni ṣe pẹlu ọrọ eto ẹkọ lapapọ lorilẹede Naijiria.

Sugbọn ibeere ti ọpọ eeyan wa n beere ni pe se ipade ti ẹgbẹ ASUU n lọ se labuja naa, yoo fi eegun otolo to aawọ yii, ti wn yoo si so ẹwu iyansẹlodi kọ abi wọn yoo papa yansẹlodi?

Awọn eeyan ti bẹrẹ si ni sọrọ lori awuyewuye IPPIS to ti di faakaja laarin ASUU ati ijọba apapọ bayii.

Ọpọ eeyan loju opo Twitter lo dẹbi ru ajọ ASUU, wọn sọ pe dundu ASUU naa ti n lata ju.

Bello El-Rufai ni tiẹ sọ pe, onijẹgudujẹra ni ajọ ASUU, ko da o ni ajọ naa nilo itusilẹ.

EL-Rufai ni pẹlu ilana IPPIS, o ṣeeṣe ki ijọba apapọ ri owo to to biliọnu mẹẹdọgbọn naira fi pamọ lori awọn oṣiṣẹ ofege lawọn fasiti ni Naijiria.

Bakan naa lawọn mii kin ọrọ El-Rufai lẹyin, wọn ni o yẹ ki ajọ ASUU naa so ewe gbejẹẹ mọwọ.

Ẹbẹ lawọn akẹkọọ n bẹ ajọ ASUU ni tiwọn, wọn ni ki wọn fiyedenu, ki wọn jẹki awọn pari eto ẹkọ awọn ki wọn to gunle iyanṣẹlodi.