Buhari Foreign Trips: Ìrìnàjò ààrẹ Buhari sílẹ̀ òkèèrè kò nípa kankan lórí ọrọ̀-ajé Nàijíríà

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad

Lẹyin ọjọ meji to de lati irinajo rẹ si orilẹ-ede Russia, Aarẹ Muhammadu Buhari tun ti mori le ilẹ Saudi Arabia bayii.

Oludamọran Aarẹ lori ọrọ iroyin, Garba Shehu ṣalaye pe aarẹ n lọ fun apero kan lori eto idokowo fun ọjọ iwaju ti wọn pe akori rẹ ni ''Ki lo kan ninu idokowo lagbaaye.''

Shehu ni eto naa yoo bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹwaa, yoo si wa sopin lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa.

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum, Abubakar Bagudu ti ipinlẹ Kebbi ati Aminu Bello Masari ti ipinlẹ Katsina ni yoo kọwọ rin pẹlu aarẹ.

Oludamọran Aarẹ, Shehu ni yoo lọ fun eto Umrah niluu Mecca lẹyin apero ti yoo waye niluu Riyadh.

Kini ero awọn eniyan kan lori irinajo aarẹ Buhari?

Amọ, onimọ ọrọ aje, Ọgbẹni Bisi Iyaniwura sọ pe irinajo Aarẹ Buhari silẹ okeere lati igba to ti dori aleefa lọdun 2015 ko tii nipa rere kan lori ọrọ-aje orilẹ-ede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad

Ọgbẹni Iyaniwura sọ pe Buhari kan ṣa n kọwọbọ iwe lasan ni pẹlu ọpọlọpọ awọn olori orilẹ-ede nilẹ okeere, ṣugbọn ko tii so eso rere kankan.

Iyaniwura ni ''gbogbo irinajo ti aarẹ Buhari ti lọ ko ti mu ki ijọba da ile iṣẹ silẹ.''

O fikun ọrọ rẹ pe aarẹ kan n nawo Naijiria lori awọn irinajo yii papaa julọ bi o ti kọwọ rin pẹlu awọn gomina.

O kepe ile aṣofin agba l'Abuja lati maa beere ipa ti irinajo Buhari yoo ni lori ọrọ aje Naijiria, nigba kuugba to ba tajo de.

Irinajo Buhari silẹ okeere

Akọsilẹ fihan pe Aaarẹ Buhari ti rinrin ajo lọ silẹ okeere nigba mọkanlelaadọta lati igba to ti di aarẹ Naijiria lọdun 2015.

Akọsilẹ iwe iroyin kan ni Naijiria sọ pe Buhari lo ida kan ninu idamẹta ọdun mẹta to kọkọ lo lọfiisi ni lati igba to ti di aarẹ lọdun 2015.

Ọpọ igba yii ni aarẹ Buhari fi wa niluu London nibi to ti n gba itọju lẹyin to ṣaarẹ.

Buhari ti rinrin ajo silẹ okeere nigba mẹrin laarin oṣu mẹta to kọja.

Lootọọ ile iṣẹ aarẹ sọ pe awọn irinajo naa ṣe pataki, ṣugbọn ọpọ ọmọ Naijiria lo sọ pe aarẹ si le ran aṣoju lọ si awọn orilẹ-ede yii k'oun le gbajumọ awọn nnkan mii nile.

Wọn ni eyi ko ba din inawo ijọba orilẹede Naijiria ku lori awọn irinajo yii ku.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad

Irinajo si orilẹ-ede Japan

Aarẹ Buhari rinrin ajo lọ si ilẹ Japan loṣu kẹjọ fun apero lori idagbasoke fun awọn orilẹ-ede ilẹ Adulawọ, TICAD7.

Ọjọ mẹfa ni aarẹ lo niluu Tokyo fun apero naa to jẹ ẹlẹẹkeje iru rẹ.

Irinajo si orilẹ-ede Amẹrika

Ninu oṣu kẹsan an ni aarẹ Buhari lọ si ilu New York fun apejọ ajọ iṣọkan agbaye to jẹ ẹlẹẹkẹrinlaadọrin iru rẹ.

Buhari ni aarẹ orilẹ-ede karun un ti yoo sọrọ nibi to ti sọrọ lori bi oju ọjọ ṣe n yipada.

Ọjọ mẹta ni aarẹ ati awọn iṣọmọgbe rẹ lo niluu New York lorilẹ-ede Amẹrika ki wọn to pada sile.

Irinajo si orilẹ-ede South Africa

Ni ibẹrẹ oṣu kẹwaa ni Aarẹ Buhari lọ si ilẹ South Africa nibi to ti ṣepade pẹlu Aarẹ Cyril Ramaphosa lẹyin iṣẹlẹ inunibini tawọn ọmọ orilẹ-ede naa ṣe si awọn ọmọ Naijiria to n gbe nibẹ.

Aarẹ Buhari fi ẹhonu rẹ han lori iṣẹlẹ ọhun ninu ipade rẹ pẹlu aarẹ Ramphosa, ọjọ mẹta ni Buhari lo nibẹ ko to pada wale.

Irinajo si orilẹ-ede Russia

Aarẹ Buhari ṣẹṣẹ de lati orilẹ-ede Russia nibi to ti lo ọjọ mẹta.

Agbẹnusọ fun ile iṣẹ aarẹ ni ọrọ eto aabo, okowo, imọ ijinlẹ ati ipese gaasi afẹfẹ idana lo gbe Buhari lọ si Russia.