INEC: Bí olóṣelú ṣe náwó lásìkò ìbò ló kàn wá, kìí ṣe pínpín èròjà oúnjẹ

Eroja ounjẹ ti awọn oloselu n pin

Oríṣun àwòrán, Other

Ajọ eleto idibo nilẹ wa ti kede pe ohun ti wọn ba fi Ẹlẹmọsọ toun sọ, ni oun maa n sọ, nitori naa, isẹ toun kọ ni lati tọpintọpin awọn eroja tawọn oloselu ba n pin fawọn araalu lasiko ipolongo ibo, lati fa oju wọn mọra.

Inec ni iwa pinpin iyọ, irẹsi, gaari atawọn eroja ounjẹ miran lasiko ipolongo ibo kii se ara isẹ awọn, idi ree ti awọn se n gboju kuro nibẹ.

Olori ẹka eto ilanilọyẹ fawọn oludibo ati ipolongo fun araalu labẹ ajọ eleto idibo nipinlẹ Bayelsa, Wilfred Ifogah lo sọ bẹẹ lasiko to n fesi si ẹsun naa, ti wọn fi kan awọn oloselu kan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oludari agba fun ikọ kan to n tọpinpin eto idibo yika ilẹ Afirika, YIAGA, Samson Itodo lo salaye fun Inec pe ni ọkọọkan ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Kogi ati ni Bayelsa, ti ibo gomina yoo ti waye laipẹ yii ni wọn ti n pin awọn eroja ounjẹ lati fa oju awọn oludibo mọra.

Itodo ni "Ajọ Inec yẹ ko se agbekalẹ eto kan nifọwọkọwọ pẹlu awọn oloselu nipinlẹ kọọkan lati ri daju pe adinku ba asa fifi owo ra ibo ati tita kaadi idibo to fi mọ oniruuru iwa aidaa miran to nii se pẹlu fifa oju awọn oludibo mọra."

Oríṣun àwòrán, @inecnigeria

Nigba to n fesi lori awọn ẹsun naa, Ifogar salaye pe "Ajọ Inec kii tọpinpin iru iwa bayii bii pinpin iyọ, irẹsi atawọn ohun miran lasiko ipolongo ibo lati ra ibo amọ awọn oloselu yii maa n fiwe pe wa lati wa tọpinpin ihuwasi wọn lasiko ipolongo ibo wọn, bakan naa si la n tọpinpin inawo wọn."

Ifogar fikun pe ẹka kan wa labẹ ajọ Inec to n ri si eto idibo, itọpinpin awọn ẹgbẹ oselu ati fifi imu finlẹ nipa owo ti wọn ba na lasiko ipolongo ibo, eyi ti wọn ti n se lasiko ti ipolongo ibo ti bẹrk nipinlẹ Kogi ati Bayelsa.