Atiku Appeal: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà yóò gbẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn PDP lọ́jọ́rùú

Atiku and Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ninu idibo aarẹ dun 2019 Naijiria n tako ijaweolubori aarẹ Buhari

Ile ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria ti da Ọjọru ọgbọn ọjọ oṣu Kẹwa to n bọ gẹgẹ bi ọjọ ti yoo gbẹjọ kotẹmilrun ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar n gbe bọwa lori idibo aarẹ 2019.

Igbẹjọ yi n waye lẹyin ti Atiku kọwe kotẹmilọrun lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun to ti waye ṣaaju.

Ẹgbẹ oṣelu PDP lo kede ọrọ yi loju opo Twitter wọn ti wọn si ni ''asiko to bayi lati doola Naijiria''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ alatako naa ni awọn ṣetan lati tako esi idibo to gbe aarẹ Buhari wọle lọdun 2019.

Ninu iwe kotẹmilọrun ti wọn fi ṣọwọ sile ẹjọ to ga julọ, wọn ni igbimọ igbẹjọ idibo naa ṣe aṣiṣe ninu idajọ wọn.

Bakan naa ni wọn sọ pe aarẹ Buhari ko sọ ootọ fun INEC nipa iwe ẹri rẹ to fi kalẹ.

Loṣu kẹsan, igbimọ olugbẹjọ idibo fọwọ rọ ẹsun ti Atiku gbe wa si iwaju rẹ pe ko fi ẹsẹ mulẹ to.

Atiku ati ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn fẹ ki ile ẹjọ to ga julọ wọgile idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun, ki wọn si kede Atiku gẹgẹ bi aarẹ.