Alága SUBEB: A ṣetán lá ti gba owó ìrànwọ́ Almajiri ní ìpínlẹ̀ Oyo

Aworan awon omode to joko sile

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile iṣẹ to n mojuto eto ẹkọ kariaye nipinlẹ Oyo ta mọ si UBE lawọn ko ti ri iwe gba lati ọdọ ijọba apapọ nipa eto iranwọ ẹkọ Almajiri ni ipinlẹ naa.

Alaga ajọ naa ọmọwe Nureni Adeniran to ṣalaye ọrọ yi fun ileeṣẹ iroyin BBC sọ pe nigba kigba to ba de,awọn ṣetan lati gba tọwọ tẹsẹ.

Laipẹ yi ni ijọba apapọ kede pe awọn ti ṣeto owo iranwọ ẹgbẹrin din meje miliọnu naira feto ẹkọ Almajiri.

Eto yi la gbọ pe ipinlẹ mẹwaa yoo jẹ anfaani rẹ ti ipinlẹ Oyo si jẹ ọkan lara wọn.

Nureni Adeniran ni lọwọ bayi, awọn eto miran wa nilẹ fawọn ọmọ ti ko si ni ile ẹkọ ti ipinlẹ Oyo ni lọkan lati ṣe.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Eto yi la gbọ pe ipinlẹ mẹwaa yoo jẹ anfaani rẹ ti ipinlẹ Oyo si jẹ ọkan lara wọn.

Nigba ti a beere lọwọ rẹ boya awọn ọmọ Almajiri wa ni ipinlẹ Oyo, Nureni ni pe wọn wa, ṣugbọn ati Almajiri ati awọn miran ti ko lọ si ile iwe ni eto naa yoo ṣe lanfaani.

''A ni awọn ọmọ Almajiri yi ni adugbo Sabo ati ni Oke Ogun. Awọn ya mi yatọ si Yoruba wa ninu wọn ṣugbọn gbogbo wọn ti da papọ mọ ara wọn''

O ṣalaye pe inu awọn dun si igbese yi ti awọn si lero pe yoo mu adinku ba iye awọn ọmọ ti ko si ni ile ẹkọ nipinlẹ naa.

Ijọba apapọ pàdí ọrẹ́ dà lori Almajiri

Ko pẹ si igba yi ni ijọba Naijiria sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ lati wọgile eto ẹkọ Almajiri ti ijọba to ṣaaju rẹ.

Ọrọ naa ṣebi fakinfa ti agbẹnusọ ileeṣẹ aarẹ Garba Shehu si pada ṣalaye pe awọn ko ni tii wọgile eto naa amọ awọn ko ni jẹ ki ohun to ba awọn ile ẹkọ Almajiri ti ijọba tẹlẹ da silẹ ṣẹlẹ sawọn naa.

O ṣalaye pe awọn yoo ṣeto tuntun eleyi ti awọn ipinlẹ tọrọ kan naa yoo da si eto wọn.

Ko ti i si alaye lẹkunrẹrẹ lori bi wọn yoo ti ṣe ṣeto yi amọ owo ti wọn fẹ naa ni wọn ti ṣe atupalẹ rẹ.

Lọdun 2019, irinwolemẹrindinlogun miliọnu Naira ni wọn yoo na, nigba ti wọn yoo na ọọdunrunlenimọkandinlọgbọn naira le diẹ ni 2020, milionu mẹrindinlogoji naira ni wọn yoo na ni 2021 ti owo ina lori eto yi lọdun 2022 si jẹ miliọnu mọkanla naira le diẹ.

Àkọlé fídíò,

Ofada Rice: kíni ẹ̀yin gbádùn nínú ìrẹsì ọ̀fadà?