Brexit: Àwọn olórí ilẹ̀ Europe fẹnukò lórí àfikún sáà tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yóò kúrò pátápátá ní EU

Asia ilẹ UK

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ isọkan orilẹede nilẹ Europe, Europian Union, ti gba lati sun asiko ti United Kingdom yoo fi ajọ naa silẹ́ patapata di ọjọ Kọkanlelọgbọn Oṣu kinni ọdun 2020, kii si se ọjọ Alamisi ọsẹ yii mọ.

Aarẹ fun igbimọ alakoso ajọ EU Donald Tusk ṣalaye pe aaye ti wa fun UK bayii lati kuro ninu ajọ EU ko to di ipari osu Kinni ti fẹnu ko le lori, eyiun ti ile asofin ba fi ọwọ si.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbesẹ naa lo waye nibayii ti awọn asofin ilẹ UK n gbaradi lati dibo lori aba ti olootu ilẹ naa, Boris Johnson gbe siwaju wọn eyi to n beere pe ki wọn fontẹ lu sise eto idibo gbogbo gboo lojọ Kejila osu kejila ọdun 2019.

Amọ ẹgbẹ oselu SNP ati Lib Dem lo ti daba saaju pe ki wọn seto idibo naa lọjọ Kẹsan osu Kejila ọdun 2019.

Amọ ijọba ko tii wọgile erongba sise idibo lọjọ ti awọn ẹgbẹ oselu naa daba rẹ, eyiun to ba kuna lati gba ontẹ ile asofin fun ọjọ to beere fun nirọlẹ oni.

Ọjọ Alamisi ọsẹ yii lo yẹ ki UK kuro ninu ajọ EU sugbọn Johnson beere fun afikun saa ti wọn yoo kuro nibẹ lẹyin ti ile asofin apapọ ilẹ naa kuna lati faramọ awọn ilana to wa nilẹ lori bi UK yoo se kuro ninu ajọ EU.

Lọpọ igba ni Johnson ti maa n tẹnumọ pe UK yoo kuro ninu ajọ EU lọjọ kọkanlelọgbọn osu Kẹwa ọdun 2019, eyiun ọjọ Alamisi ọsẹ yii tii se gbedeke ọjọ to da, eyi to ni yoo jẹ lẹrọ abi ni tipa, sugbọn ofin ti paa lasẹ fun lati gba aba ọhun.

Tusk yoo wa beere ohun ti ilẹ UK fẹnuko le lori lori kikuro rẹ ni EU, lati ipasẹ iwe kan ti yoo kọ laarin awọn orilẹede mẹtadinlọgbọn miran to wa ninu ajọ EU, eyi to seese ko fi ransẹ lọjọ Isẹgun abi Ọjọru, ko to di pe o fontẹ lu afikun saa ti UK yoo lọ naa.

Aago mẹrin irọlẹ oni ni awọn asofin ni Uk yoo dibo lori igba ti eto idibo olootu Ijọba ilẹ Gẹẹsi yoo waye.