Foluke Daramola: Ìgbé ayé gbajúmọ̀ gbọdọ̀ ṣèwúrí fún àwọn èèyàn láti dé ibi gíga

Foluke Daramola Salako

Oríṣun àwòrán, @facebook

Saa laa ni, ẹnikan ko nile aye nitori igba lasọ, igba lẹwu, igba kan n lọ, igba kan si n bọ, aye ko duro soju kan.

Boya eyi ni gbajumọ osere tiata kan lobinrin, Folukẹ Daramọla Salakọ ro, to fi kọ̀ ironu akewi soju opo Instagram rẹ, eyi to fi n gba awọn akẹẹgbẹ rẹ nimọran nipa igbe aye rere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Foluke ni ko si bi eeyan kan se lero pe oun gbajumọ to, saa ni yoo ni, ti irawọ rẹ yoo si tan fun igba kan nitori ko lee jẹ irawọ ti yoo tan fun gbogbo igba.

O ni awọn irawọ atijọ yoo wọọkun lọjọ kan, ti awọn irawọ tuntun yoo si maa dide bii itanna lawọn akoko kan.

Osere tiata naa ni ojoojumọ ni wọn n bi awọn irawọ tuntun, ti awọn irawọ kan si n jade laye, amọ ohun to se pataki ni pe ki eeyan jẹ gbajumọ to pegede.

O ni iru ẹni bẹẹ gbọdọ jẹ ẹni to n ko ipa gidi si awujọ to wa, ati ẹni ti eeyan lee gbẹkẹle, ti wọn yoo si maa gboju soke wo lọọkan bii awokọse rere gẹgẹ bii iwuri ati koriya lati de ibi giga, tabi ẹni to n huwa rere, ti wọn lee wo lati se imusẹ awọn afojusun wọn nile aye.

Oríṣun àwòrán, folukedaramolasalako

Daramola ni Gbajumọ kii se gbajumọ gidi ti igbe aye rẹ ko ba lee se iwuri fun awọn ẹlomiran lati se lakaka fun ohun to dara ti wsn n fẹ laye.

O wa kadi asamọ rẹ nilẹ pe gbajumọ ko nilo lati maa tẹ ifẹ awọn eeyan kan lọrun ki wọn lee nifẹ rẹ nitori irufẹ igbe aye to n gbe ati awọn aseyọri rẹ, amọ o yẹ ko lee se koriya fawọn ẹlomiran lati lakaka de ibi giga.