Fọ́tò ló ṣàfihàn ibi tí ọmọ ti Nọọsi jígbé lódún 1997 wà

Cassidy Nurse
Àkọlé àwòrán,

Aworan fọto àdáyà to kọkọ ṣafihan awọn mejeeji papọ

Osu Kini, ọdun 2015 ni ọmọbinrin ọdun mẹtadinlogun to n lọ ile iwe girama Zwaanswyk High School ni ilu Cape Town ri ohun iyanu!.

Cassidy Nurse ni ọdọbinrin naa to woye pe ẹni ti oun ṣẹṣẹ pade yii ti jọ oun ju.

Ona ile iwe naa nibi ti o ti pade ọmọbinrin miran, Miché Solomon to sẹsẹ wọ ile iwe wọn.

Gbogbo eniyan to ri awọn mejeeji lo sọ wi pe wọn jọ ibeji, ti Miche is sọ wi pe ni se lo dabi ẹni pe awọn ti mọ ara wọn fun ọpọlọpọ ọdun, ti ọdun mẹta to wa laarin ọjọ ori wọn ko si jẹ idiwọ tabi idena fun wọn.

Oríṣun àwòrán, MPHO LAKAJE

Àkọlé àwòrán,

Miche Solomon lasiko yii

Bawo ni aṣiri ṣe tu pe ibeji ni wọn?

Lẹyin ipade yii ni awon mejeejidi ọrẹ ti wọn si maa n so fawon eniyan to ba beere lowo won pe se ibeji ni won pe awon ko mo, amo boya ni aye miran ibeji ni awọn.

Ni ọjọ kan, ni awọn mejeeji ba jọ ya fọto àdáyà papọ, ti awọn obi Cassidy si bẹrẹ si ni beere lọwọ Miche boya Ọgbọn ọjọ, Osu Kẹrin, ọdun 1997 ni wọn bi? ti o si sọ wi pe lootọ igba naa ni wọn bi oun.

Lẹyin ọsẹ diẹ ni awọn ọga ile iwe naa pe Miche si inu oọfisi ọga ile iwe naa ti wọn si sọ fun un wi pe nise ni wọn ji i gbe ni ọmọ ọwọ ni ile Iwosan ti wọn ti bii, Groote Schuur ni Cape Town.

Wọn tun sọ fun un pe orukọ rẹ ti wọn sọ ọ ni Zephany Nurse.

Amọ Michel ko gbagbọ, o tilẹ ba wọn jiyan wi pe ile iwosan Retreat Hospital ni wọn ti bi oun, nibi ti ko jina si ile iwosan ti wọn sọ wi pe wọn ti bii.

Oríṣun àwòrán, Image copyrightHUISGENOOT/NONCEDO MATHIBELA

Àkọlé àwòrán,

Celeste Nurse ati Cassidy abilekeji ọmọ rẹ

Miche gba ki wọn se iwadii ẹjẹ rẹ nipa DNA, ti iwadii naa si fihan pe looto Zephany Nurse ni wọn ji gbe ni ọdun 1997.

Ọmọbinrin naa sọ wi pe ẹru ba oun nigba ti oun gbo gbogbo iroyin naa.

Ninu iwadii ni wọn ti rii pe ohun to wa ninu iwe ẹri ọjọ ibi Zephany kii ṣe otitọ rara nitori pe wọn ko ri akọsilẹ rẹ ni ile iwosan Retreat Hospital ti wọn ni wọn bii si.

Àkọlé àwòrán,

Miche nigba ti o wa lọmọ oṣu mẹjọ pẹlu Michael

Lẹyin eyi ni wọn ri aridaju pe wọn ji Zephany gbe nile iwosan Groote Schuur ti wọn bii si ni Cape Town.

Bakan naa ni o gbọ wi pe iya rẹ to to tọ ọ dagba, Lavona Solomon wa ni panpẹ ọlọpaa, ti ọkan rẹ si daru pẹlu ibeere pe ki lo sẹlẹ, bawo lo se sẹlẹ? kilode ti wọn se ṣe bẹẹ?

Amọ, o ni wi pe iwadii fihan wi pe baba to tọ oun dagba ko mọ nkankan nipa bi wọn se ji oun gbe rara, ti awọn ọlọpaa si fi i silẹ pe ko maa lọ ni alaafia.

Àkọlé àwòrán,

Lavona Solomon nile lẹyin to ni oun bimọ tuntun

Ọdun 2016 ni wọn ran Lavona lọ si ẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun ijinigbe ati aibọwọ fofin to tẹ itọju ọmọ kekere mọlẹ.

Lasiko igbẹjọ Lavona, o ni wi pe nọọsi ti orukọ rẹ n jẹ Sylvia, ti o n fun oun ni itọju iwosan ki oun le bimọ lasiko lo lọ gbe ọmọ jojolo naa wa, ti o si sọ fun oun pe iya rẹ kọ ọ silẹ ni.

Amọ ile ẹjọ ko ri aridaju lori nọọsi naa, ti ko si si ẹri pe eniyan kan n jẹ orukọ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lavona Solomon (to bo oju re) nile ẹjọ ni Cape Town lasiko to n wọnu ile ẹjọ lọ fun igbẹjọ

Bi o tilẹ jepe Lavona sọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, Miche sọ wi pe oun ko gbagbọ pe iya to toju oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

O ni pe o lera fun oun lati darapọ mọ awọn idile tuntun ti iwadii fihan wi pe awọn gan an lo bi oun, amọ oun n tiraka diẹ diẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Noosi Morne to jẹ baba Zephany gangan nigba ti o n jade nile ẹjọ lẹyin ti Adajọ ti dajọ

Miche Solomon to jẹ orukọ ti wọn sọ ọ ni kekere ni o n jẹ, amọ o sọ wi pe o tẹ oun lọrun ki awọn eniyan pe oun ni Zephany naa, nitori orukọ oun gangan niyẹn.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Michael ati ọmọ Miche nigba ti wọn n lọwo Lavona ni ọgba ẹwọn