Gbogbo ipá kò tíì pin lórí ọmọ ọdún méjì tó kó sí àǹga

Baba ati Iya Sujith

Oríṣun àwòrán, BBC Sport

Àkọlé àwòrán,

Ebi ọmọ to ja si kọnga

Ni bayii, awọn adoola ẹmi ẹni ko tii ri ọmọ ọdun meji ti o ja si inu kọnga gbe jade ni ilẹ India.

Oni lo di ọjọ kẹrin ti wọn ti n gbiyanju lati doola ẹmi ọmọde yii to ko si kanga.

Sujith Wilson ni orukọ ọmọde to n ṣere ni eti kanga ni bii iwọn ẹsẹ bata ọgbọn si kanga naa ni agbegbe Tamil Nadu ni orilẹ-ede India.

Ko pé ni wọn deede gbọ ariwo rẹ to n ja sinu kọnga ti o jin to ọgọsan an mita silẹ.

Awọn adoola ẹmi naa fi atẹgun inu igo si ara ọmọ naa ti o wa ninu kọnga ọhun, bo tilẹ jẹ pe wọn ko le sọ pato ipo ti ọmọ naa wa.

Sibẹ wọn ti gbe koto si ẹgbẹ kọnga ti ọmọ naa ko si, wọn si n fi ẹrọ igbalode fa omi inu kanga naa sita.

Lọjọ Ẹti ni Sujith ko si kanga nigba ti o n ba awọn ọrẹ rẹ ṣere.

Itara abiyamọ n mu iya Sujith bayii de ibi pe wọn kiyesi pe o lọ n ran apo to ro pe oun a lo fi yọ ọmọ oun sita ninu kanga to ko si.

Awọn Akọroyin ṣalaye pe, ni kete ti iṣẹlẹ naa waye ni iya rẹ ti bẹrẹ si n pe e ṣugbọn ti ko si dahun.

Isṣẹlẹ yii ti pe akiyesi ọpọlọpọ awọn eniyan ilẹ naa si ni eyi ti Olootu Ijọba, Narendra Modi si ti fi si ori ẹrọ ayelujara ni ọjọ Aje ibi ti iṣẹ didoola ẹmi ọmọ naa de duro bayii.