Òyìnbó lásán ni 'consequential adjustment' ẹ ò tún gbọdọ̀ gé owó oṣù ní ìpínlẹ̀ mọ́ - NLC

NLC

Oríṣun àwòrán, Huw Evans picture agency

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ NLC ti ní N33,000 ni gbèdéke owó osù òsìsẹ́, lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ májẹ̀kóbàjẹ́ fi ọwọ́ sí N27,000.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria ni ipinlẹ Oyo ti fesi si ọrọ awọn Gomina Naijiria ti wọn ni ijọba apapọ ko le mu awọn nipa lati san afikun owo oṣu oṣiṣẹ tuntun nipinlẹ wọn.

Alaga ana fẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo Comrade Siyanbade Waheed Olojede ni nibi ti ọrọ de duro yii, ko tọ ki awọn Gomina yẹ adehun lori ọrọ owo oṣiṣẹ mọ.

Siyanbade ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba sọ pe ''boju ba yẹju, ko yẹ ki ijọba yẹ ohun pẹlu awọn.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Àkọlé àwòrán,

Awọn ijọba ipinlẹ kan n wa ibinu ẹgbẹ osisẹ ni, awa naa si ti setan fun wọn

Alaga oṣiṣẹ tẹlẹ ri sọ pe gbogbo ijiroro to yẹ ki o waye lawọn oṣiṣẹ ti ṣe pẹlu ijọba apapọ ti wọn si ti fara da gbogbo aba ti ijọba mu wa nipasẹ adinku lori iye ti awọn beere.

O ni lopin igba ti owo tawọn Gomina naa n gba lowo oṣu ko yatọ lati ipinlẹ kan si omiran ko yẹ ki wọn maa sọrọ nipa gige owo oṣu nipinlẹ kan si omiran.

''Ọna a ti mu oṣiṣẹ lẹru ni gbogbo oyinbo ti wọn sọ nipa "consequential adjustments". Ki wọn to fẹnuko lori iye owo yii, ko si ẹni ti ko ṣoju rẹ ninu awọn Gomina. Ki lo wa de ti wọn n sọ pe awọn tun fi lọ joko idunadura mii?

''Ko bojumu a o si ni fẹ ki wọn maa roko si ibi ti wọn sọrọ si''

Oríṣun àwòrán, Inside Oyo

Comrade Siyanbade wa rọ awọn oṣiṣẹ lati san bantẹ wọn ko le daada nitori ọrọ to wa nilẹ yoo gba ki wọn gbaruku ti ẹgbẹ oṣiṣẹ.

O sọ pe laiṣe bẹ, mudunmudun to yẹ ki oṣiṣẹ jẹ lori ẹkunwo oṣu ko ni jẹ ti wọn.

Ìjọba ìpínlẹ̀ ń wá ìbínú òṣìṣẹ́ bí wọn kò bá san àlékún owó oṣù tuntun - TUC

O seese ki alekun owo osu fawọn osisẹ ni Naijiria fori sanpọn ni ọpọ ipinlẹ to wa lorilẹede yii nitori awọn gomina ti kede pe awọn ko lee sanwo ju agbara awọn lọ, bi ọwọ awọn ba se mọ ni eku awọn yoo se fi họri.

Alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria, tii tun se gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi lo sisọ loju ọrọ naa lẹyin ipade awọn gomina to waye lọjọ Aje nilu Abuja.

Fayẹmi ẹni to sọ pe igbimọ alasẹ ijọba orilẹede yii ko lee se ipinnu nipa sisan owo osu tuntun naa fun awọn ipinlẹ tun salaye siwaju pe ijọba apapọ ko ro tawọn ijọba ipinlẹ rara lasiko to fi n seleri pe oun yoo san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo osu to kere julọ fawọn osisẹ.

Fayẹmi ni "Ijọba ipinlẹ kọọkan lo ni igbimọ alasẹ tiẹ, to jẹ igbimọ to ga julọ lati fẹnuko lori ipinnu sise, awọn ẹgbẹ osisẹ naa si wa lawọn ipinlẹ ti wọn yoo joko dunadura lori owo osu tuntun, nitori naa, ohun ti agbara wa ba ka laa se.

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Àkọlé àwòrán,

Musa Lawal ti wa kesi Fayẹmi pe ko sọ ọrọ ẹnu rẹ nitori awọn ọrọ kobakungbe to ba sọ lee fa ibinu awọn ẹgbẹ osisẹ.

Wayi o. Akọwe apapọ fun ẹgbẹ osisẹ NLC, Ugboaja ti wa fesi pada fun Fayẹmi pe ko si ipinlẹ kankan ti yoo sọ pe kii se ori sisan ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira bii owo osu to kere julọ, ni koko idunadura pẹlu ẹgbẹ osisẹ.

"Ikọọkan ipinlẹ ni yoo dunadura lootọ bi agbara ọrọ aje wọn ba se ka a, sugbọn ohun to ja ju ni pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni yoo jẹ owo osu to kere julọ ti osisẹ kan yoo gba nipinlẹ wọn, amọ bi wọn yoo se wa yọ sira wọn pẹlu awọn lọgalọga osisẹ ku saarin ẹgbẹ osisẹ ati ijọba nipinlẹ kọọkan."

Oríṣun àwòrán, @NLCHQ_ABUJA

Àkọlé àwòrán,

Awọn ijọba ipinlẹ kan n wa ibinu ẹgbẹ osisẹ ni, awa naa si ti setan fun wọn

Sugbọn lero ti akọwe apapọ fun ẹgbẹ osisẹ TUC, Origi Musa Lawal ti wa kesi Fayẹmi pe ko sọ ọrọ ẹnu rẹ nitori awọn ọrọ kobakungbe to ba sọ lee fa ibinu awọn ẹgbẹ osisẹ.

Musa-Lawal ni "Awọn ijọba ipinlẹ ni asoju ninu idunadura naa, ko si lee di akoko yii ki wọn wa sẹ lori ojuse wọn. Wọn kan n wa ibinu ẹgbẹ osisẹ ni, awa naa si ti setan fun wọn."