Owu Water Falls: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì

Awamaridi ni isẹ Olodumare, to ba se ojo, a se ọda, a se ọkan a mu bi otutu, a se omiran, a mu bi ọyẹ.

Aramọnda isẹ Olodumare miran lo tun kalẹ silu Ọwa Kajọla nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Kwara nibiti omi isẹda kan ti n da lati ori oke wa si isalẹ.

Omi naa,Ówù Water Falls to ga ni iwọn mita ọgọfa la gbọ pe o jẹ eyi to ga julọ nilẹ Afirika, ibẹ si ni awọn baba nla to sẹ ilu Ọwa Kajọla silẹ tẹdo si lasiko ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọba Solomon Oyewọle Asinbiorin Keji kaanu pe bi o tilẹ jẹ pe ibudo irin ajo afẹ to lagbara ni ibudo naa jẹ, sibẹ ko si ijọba oloselu kankan nipinlẹ naa, to satunse ibudo ọhun.

Ọba Oyewọle fikun pe oju ọna to wọ ibudo naa buru jai lai naani ọpọ ohun alumọni to sodo si agbegbe omi Ówù ọhun.