Viemens Bamfo: Ọmọ ọdún méjìlá tó gbèlé kẹ́kọ̀ọ́ dì àpéwò bó tí ṣé wọ ilé ẹ́kọ́ fásítì Ghana

Viemens Bamfo

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ọmọ ọdun mejila kan lorileede Ghana ti di ilumọka lẹyin to pegede idanwo, ti wọn si gba wọle si fasiti orilẹede Ghana.

Ọmọdekunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Bamfo, ni akẹkọ ti ọjọ ori rẹ kere julọ laarin awọn bi ẹgbẹrun mẹta din ọgọrun, to n gbele kawe ti wọn gba wọle si fasiti naa lọdun yii.

Nigba to pari ile iwe alakọbẹrẹ lawọn obi rẹ bẹrẹ si ni gbele kọ ni ẹkọ, lẹyin igba naa lo kọ idanwo ile ẹkọ girama WASSCE to si pegede.

O ti bẹrẹ si ni kawe lati gboye ẹkọ iṣakoso oṣiṣẹ ọba ni fasiti Ghana to wa nilu Legon.

Oríṣun àwòrán, Kenny Senaya/Facebook

Awọn eeyan bẹrẹ si ni semọ ọmọdekunrin naa loju opo ayelujara pẹlu bi ko ti ṣe lọ si ile iwe girama, amọ ti o si fakọyọ ninu idanwọ ile iwe girama to tun wọ fasiti lọmọ ọdun mejila.

Gẹgẹ bi ohun to sọ, o ni ohun fẹ di aarẹ orileede Ghana ni ẹni ogoji ọdun lọjọ iwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: