Kogi Prison: Kò sí ẹ̀mí kankan tó nù, a sì tí rí lára àwọn tó fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ

Abawọle ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Others

Awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn agbegbe Koton-karfe ni ipinlẹ Kogi ti ẹkun omi ti ṣọṣẹ ni awọn ti ri lara awọn ẹlẹwọn to sa lọ pada ko si si ẹmi kankan to nu.

Latari ẹkun omi yii lawọn ẹlẹwọn fi fẹsẹ fẹ ẹ nigba ti wọn rii pe ogiri ibi ti wọn ko wọn pamọ si ti ya.

Ninu ọrọ ti ọgbẹni OF Enobore fọwọ si lorukọ ileeṣẹ naa, oludari agba ile iṣẹ to n ṣamojuto awọn ọgba ẹwọn ni Naijiria, Ja'afaru Ahmed paṣẹ pe ki wọn ko awọn ẹlẹwọn naa lọ sibomii kiakia.

Mọjumọ ọjọ Aje yii ni ojo naa ṣakoba fun odi ti wọn mọ yika ọgba ẹwọn ọhun, tawọn ẹlẹwọn si fẹsẹ fẹ.

Lasiko ti iṣẹlẹ yii waye, iye ẹlẹwọn ti ọgba ẹwọn yii ni jẹ ọtalerugba o din mẹta. Torinaa, nigba ti awọn to sa lọ lo anfani ẹkun omi to ya ogiri sa lọ, awọn marunlelọgọrun duro sinu ọgba lai sa lọ.

"Ni bayii, a ti ri mẹẹdọgbọn pada ninu awọn to sa lọ o ṣi ku marundinlọgọrun sita ti a o tii mọ ibi ti wọn wa".

Gbogbo akitiyan ijọba ipinlẹ Kogi atawọn oṣiṣẹ alaabo gbogbo kaakiri Naijiria to fi mọ awọn figilante ibilẹ lo n ṣeranwọ fun ẹka aabo yii lati ṣawari awọn ti wọn ko tii ri.

Oludari agba ile iṣẹ to n ṣamojuto awọn ọgba ẹwọn ni Naijiria ti wa fọrọ sita si awọn araalu lati dakun pese ọrọ to ba wulo ti wn ba ri to lee muṣẹ ya lati ri awn to sa lọ yii pada.Ojo arọọrọda to ya ogiri ọgba ẹwọn nilu Koton Karfe nipinlẹ Kogi, ti mu ki awọn ẹlẹwọn aadọjọ salọ mọ awọn ọga ẹlẹwọn lọwọ.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ lati ẹnu alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi, ikọ awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa ati awọn ajọ ori lalakanfinsọri lo dijọ n wa awọn ẹlẹwọn to na papa bora yii.

Ile isẹ akoroyinjọ ni Naijiria (NAN) sọ pe, ọga agba fun ile iṣẹ to n sakoso awọn ọgba ẹwọn ni Naijiria, ọgbẹni Jafar Ahmed lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fawọn akọroyin nilu Koton Karfe.

Ahmed sọ pe awọn ẹlẹwọn okoolenigba ati mẹjọ lo wa ni ọgba naa nigba ti ẹkun omi naa ya wọ ibẹ.

Oríṣun àwòrán, @NLCtoday

O tẹsiwaju pe, lọwọlọwọ ọgba ẹwọn naa ko ti ṣe gbe pada, tori naa, wọn ti gbe awọn ẹlẹwọn ibẹ lọ si ibomiran titi ti omi yoo fi gbẹ nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ipenija ẹkun omi kii ṣe ohun tuntun lagbegbe Koton Karfe, to sun mọ ilu Lokoja nibi ti odo Benue ati Niger ti pade.

Loṣu Kẹfa ọdun to lọ, o le ni ọgọsan ẹlẹwọn ti awọn agbebọn tu silẹ ni ọgba ẹwọn Koton Karfe yii kanna.

Oluranlọwọ si Gomina ipinlẹ Kogi lori ọrọ aabo, Jerry Omadara naa sọ pe, o le ni ọgbọn awọn ẹlẹwọn to salọ ti awọn ti ri mu pada.

Ko ti si iroyin nipa ibi ti awọn ẹlẹwọn to ku wa tabi boya ọwọ ti tẹ wọn.