Kogi elections: Ilé ẹjọ́ ní ẹgbẹ́ AA kùnà ìlànà INEC fún ìbò gómìnà ní Kogi, Bayelsa

Ami idanimọ ẹgbẹ oṣelu Action Alliance

Oríṣun àwòrán, @AllianceAa

Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja ti paṣẹ pe ẹgbẹ oṣelu Action Alliance (AA) ko lẹtọ lati fa oludije silẹ fun eto idibo sipo gomina ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Adajọ Inyang Ekwo to gbe idajọ naa kalẹ ni ẹgbẹ oṣelu AA ko tẹle awọn alakalẹ ajọ eleto idibo INEC, lori fifi orukọ oludije silẹ fun eto idibo naa, ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019.

Ileẹjọ naa ni ilana ti ajọ INEC fi sita ni pe ki orukọ gbogbo awọn oludije to ti wọle sikawọ ajọ naa, o pẹ ju, agogo mẹfa irọlẹ ọjọ kẹsan oṣu kẹsan ọdun 2019.

Adajọ Ekwo ni nitori idi eyi, ẹjọ ti awọn oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun ipinlẹ Bayelsa ati Kogi, Ebi Peretiemo ati Samuel Alfa pawọ pọ pe ko lẹsẹ n lẹ.

Ekwo fikun pe, awọn oludije mejeeji ko lee fi ẹri mulẹ pe lootọ ni awọn wa ni olu ileeṣẹ ajọ INEC lọjọ naa ati pe oṣiṣẹ ajọ naa lo kọ lati gba iwe iforukọsilẹ wọn, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.