Osogbo Police: Ọwọ́ tẹ ṣọ́jà mẹ́ta tó ya bo iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, àwọn yókù sálọ

Awọn ọlọpaa lori ọkọ ayẹta

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Iroyin kan sọ pe awọn ṣọja kan ya bo olu ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun nilu Oṣogbo ni ọjọ Aje.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awọn ologun naa ti ja ilẹkun olu ileeṣẹ ọlọpaa naa, ti wọn si ti da hilahilo silẹ lagbegbe naa, ki o to di pe awọn ọlọpaa kapa wọn ti wọn si ko awọn mẹta sahamọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti BBC News Yoruba pe alukoro olu ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oṣogbo, o ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi ero rẹ lori iṣẹlẹ naa sọwọ sawọn oniroyin ninu atẹjade laipẹ.

Awọn mẹta ninu awọn ṣọja naa to ti tasẹ agẹrẹ wọle si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni wọn mu pẹlu panpẹ ofin, ti wọn si gba ohun ija ọwọ wọn ti awọn ti awọn akẹgbẹ wọn yoku si pada.

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Titi di bi a ṣe n sọrọ yii, ko tii si ẹni to lee sọ ni pato ibudo ologun ti awọn ologun naa ti wa, ṣugbọn ohun ti o daju ni pe, ibudo ologun to sunmọ olu ileeṣẹ ọlọpaa naa julọ ni ibudo ologun fawọn onimọ ẹrọ to wa nilu Ẹdẹ.

Amọ ko tii si ẹni to lee fi idi rẹ mulẹ pe nibẹ ni awọn ologun yii ti wa.

Bakan naa ni iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ tun jẹ ko di mimọ pe, ṣọja kan ti awọn ọlọpaa mu lọjọ Satide laarin igboro ilu Osogbo to si wa ni ahamọ awọn ọlọpaa titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, lawọn akẹẹgbẹ naa fẹ lọ gba silẹ.