Oyo Schools: Iléẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ́ gba ₦126m, tí girama gba ₦400m owó ẹ̀náwó

Gomina Seyi Makinde n ba akẹkọ kan sọrọ ni yara ikẹkọ Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Gomina ipinlẹ Oyọ Onimọ ẹrọ Ṣeyi Makinde ti fọwọ si sisan owo to to okoolelẹẹdẹgbẹta ati mẹfa miliọnu naira (₦526) fun gbogbo ile iwe ijọba gẹgẹ bi owo ẹnawo atigbadegba fawọn ileewe ijọba bii ẹgbẹrun meji aabọ.

Atẹjade kan tijọba fisita lo sisọ loju ọrọ yii pẹlu afikun pe wọn ti fi owo to to irinwo miliọnu naira (₦400m) ṣọwọ si awọn ile iwe girama, nigba ti ile iwe alakọbẹrẹ naa si ti tẹwọ gba aadoje miliọnu naira o din mẹrin ( ₦126m) bakan naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Owo yii ni Ijọba lo wa fun ẹnawo atigbadegba awọ̀n ileewe naa fun taamu akọkọ ninu saa eto ẹkọ ọdun 2019 si 2020, ti wọ̀n si ti pasẹ fawọn ọga agba ileẹkọ alakọbẹrẹ ati girama naa lati lọ si apo asuwọn owo ni banki ki wọn lee gba owo naa ni kiakia.

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Ojilelẹgbẹta ile iwe girama lo wa yika ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si ti n jẹ mula owo iranwọ naa eyi to n pese ẹgbẹrun kan naira ni fun akẹkọ kan ni taamu kan.

"Ti irinwo akẹkọ ba wa nileewe kan, ta si n pese ẹgbẹrun kan naira fun itọju akẹkọ kọọkan, a jẹ pe ijọba yoo maa na miliọnu lọna irinwo naira ni taamu kan lawọn ileẹkọ girama. Apapọ isiro owo yii yoo si ku si biliọnu kan ati miliọnu lọna igba naira (₦1.2bn) fun saa eto ẹkọ kan fawọn akẹkọ girama."

Ijọba ipinlẹ Ọyọ wa rọ awọn eeyan ti eto yii gberu lawọn ileẹkọ ijọba lati lo owo naa bo se yẹ .

Image copyright @OfficialSeyiMakinde

Bakan naa lo ni o yẹ ko ye wọn pe ijọba yoo beere nipa bi wọn se naa owo naa, ti yoo si fiya to jogbin jẹ ẹnikẹni to ba gbidanwo lati ya kuro loju opo ilana ipese ojulowo ẹkọ ọfẹ tabi to n dọgbọn gba owo kotọ lọwọ awọn akẹkọ.