Fake News: Lai Mohammed fa ọmọ Nàìjíríà létí lórí ìròyìn òfégè

Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, LAi Mohammed/Facebook

Àkọlé àwòrán,

À ń ṣọ́ọ yín lórí ayélujára

Minisita eto ibanisọrọ ati iroyin lorilẹede Naijiria, Lai Mohammed ti ni ijọba yoo bẹrẹẹ ṣiṣe amojuto atagba oju opo ayelujara bayii.

Igbesẹ yii ni lati ṣe afọmọ oju opo ayelujara ki adinku lee ba ayederu iroyin atawọn ọrọ kobakungbe to n jẹyọ.

Lai Mohammed sọ ọrọ yii nibi ipade oniroyin kan to waye nilu Abuja.

Àkọlé fídíò,

Nigeria Independence Day: Wo ìlérí tí àwọn ènìyàn ṣe

Minisita ni eyi ko yọ awọn oniṣẹ iroyin silẹ o. O ni ile iṣẹ iroyin to ba ta fele fele gan yoo fara ko o.

Atunṣe ti wọn fẹ bẹrẹ yii yoo tan de oju opo ayelujara eyi to ṣapejuwe pe "o ti kọja atunṣe".

Lai Mohammed tun ni "lati igba ti a ti ṣe ifilọọlẹ eto ayipada yii ni awọn ọmọ naijiria kan ti kan si wa pe ki a boju wo bi a ṣe le ṣe ilanilọyẹ lori awọn ayelujara naa a ko si ni pa eleyi ti".

Mohammed ni ko si ijọba gidi kan ti yoo joko kawọ gbera ki iroyin ofege si maa fo kiri toun tọrọ alufansa eleyi to lee dana sun orilẹede lai si ayẹwo kankan.

"Idi niyii ti ao fi maa koju ayederu iroyin ati ọrọ alufansa ayafi bi a ba to le gbogbo rẹ danu". O ni tori awọn ti ṣe agbekalẹ igbimọ kan ti aarẹ Buhari fọwọ si lati kọju awọn ọrọ alufansa.

Àkọlé fídíò,

Owu Water Fall: Ọba Oyewole ni ibùdó ìrìn àjò afẹ́ gidi ni àmọ́ ọ̀nà ibẹ̀ burú jáì