Lola Omolola FIN: A gbọ́dọ̀ dìde láti ran àwọn obìnrin tó ń la ìwà ipá nínú ìdílé kọjá lọ́wọ́

Lola Omolola FIN: A gbọ́dọ̀ dìde láti ran àwọn obìnrin tó ń la ìwà ipá nínú ìdílé kọjá lọ́wọ́

Iwa ipa to n wọpọ lawujọ si atọmọde ati agba obinrin lo ti di irawọ ọsan to n bawọn agba lẹru bayii, eyi to yẹ ki gbogbo wa dide lati mojuto.

Idi ree ti obinrin takuntakun kan, Lola Omolola se da ẹgbẹ agbarijọpọ awọn obinrin kan silẹ lori ayelujara ti wọn n pe ni FIN, to si ni ọmọ ẹgbẹ to fẹẹ to ẹgbẹrun lọna ọgọrun lori ikanni Facebook nikan.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Lola Omolola salaye pe idi ti oun fi da ẹgbẹ FIN silẹ ni lati fun awọn obinrin lanfaani lati ko ara wọn jọ, ja fun ara wọ, ki wọn si lee jiroro lori awọn isẹlẹ to n sẹlẹ si ọkọọkan wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Omolola ni airin lọwọọwọ nii jẹ ọmọ ejo niya, amọ ti awọn obinrin ba dide tako awọn iwa ipa ti awọn ọkunrin n hu si wọn ni awujọ, adinku yoo ba iya to n jẹ wọn.

Nigba to n sọ ọna abayọ si asa hihu iwa ipa ninu idile, oludasilẹ ẹgbẹ obinrin FIN wa rọ gbogbo awọn eeyan to ba n koju iru iwa aidaa yii lati sọrọ sita, nitori iru iwa bayii kii se eyi ti a n de mọ abẹ asọ.

O si tun rọ awujọ wa lati dẹkun nina obinrin tabi dẹyẹ si wọn, bẹẹ ni ko yẹ ki wọn maa ri obinrin bii ẹni ti ko ni ọpọlọ tabi ti ko gbọn lati se ipinnu.