Border Closure: Oshiomole ní kí Vietnam wá dá oko ìrẹsì sílẹ̀ ní Nàíjíríà ni èsì ẹ̀bẹ̀ rẹ̀

Ẹnu bode Naijiria ti wọn ti pa

Oríṣun àwòrán, @CustomsNG

Bi ijọba Naijria se gbe awọn ẹnu ọna abawọle si orilẹede yii tipa ti n mu ki ori ta awọn orilẹede to mule ti wa ati awọn to wa nilẹ okeere.

Koda isoro yii pọ to bẹẹ fun orilẹede Vietnam to fi gbe asoju dide pe ko wa rawọ ẹbẹ sijọba Naijiria lati si ẹnu ibode rẹ pada, ki oun lee ko irẹsi oun wọle lọpọ yanturu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji Olootu ijọba Vietnam, Vuong Dinh Hue to ko awọn asoju naa wa sorilẹede Naijiria ti wa n rawọ ẹbẹ si ẹgbẹ oselu APC to n tukọ ijọba Naijiria lọwọ lati bawọn bẹ aarẹ Muhammadu Buhari, ki ẹnu bode wa lee di sisi pada.

Oríṣun àwòrán, @CustomsNG

Ilu Abuja ni igbakeji Olootu ijọba Vietnam naa ti rawọ ẹbẹ yii lasiko to sabẹwo si alaga ẹgbẹ oselu APC nilẹ wa, Adams Oshiomole lọọfisi rẹ, to si tun kede pe nitori bi ọrọ naa se ka awọn lara to, awọn yoo tun lọ dirẹbẹ niwaju igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọsinbajo lori rẹ pẹlu.

Nigba to n ki awọn alejo rẹ kaabọ silẹ yii, to si n fesi lori ibeere wọn, Adams Oshiomole ni are ko selu, ki wọn ma fise han wa ni Naijiria nitori bayi ni n o se nkan mi ko lee yipada, bi ohun gbogbo tilẹ pada.

Oshiomole ni orilẹede Naijiria ko lee dahun si ẹbẹ wọn lati si ẹnu bode wa, to si rọ awọn asoju ilẹ Vietnam pe ki wọn wa gba ilẹ sorilẹede Naijiria lati da oko irẹsi ni yoo pe wọn.

Oríṣun àwòrán, @CustomsNG

O ni ọmọja ti kuro niye ti ana, nitori Naijiria ko ni jẹ aatan mọ fun awọn orilẹede kan, ti wọn yoo wa maa da eroja oloro asekupani wọn si ati awọn eroja to ti bajẹ.

Alaga ẹgbẹ APC fikun pe digbi ni agadagodo yoo wa lawọn ẹnbu bode wa titi tawọn orilẹede to mule ti wa yoo fi bọwọ fun ofin to de ibasepọ okoowo laarin orilẹede kan si ekeji.