Fruits and Vegetables: Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ó yẹ ko se Carrot rẹ, ko tó jẹ ẹ́

Eso ati Ewebẹ to yi wa ka

Oniruuru ounjẹ ni asẹda fi jinki wa nilẹ Yoruba, orilẹede Naijiria ati nilẹ adulawọ lapapọ.

Ọpọ awọn ounjẹ yii lo n sofo danu ni ayika wa, ti a ko ka wọn si, ọpọ wọn si lo lee wo awọn eeyan san lọwọ oniruuru arun to n ba wọn ja lai se wahala kankan, ti yoo si tun mu ki agọ ara wa ji pepe.

Lara awọn ounjẹ yii la ti ri eso Carrot, ewe Lettuce, eso Cucumber ati Avocado pear eyi ti wọn ni eroja asaloore ti wọn n pọ sinu agọ ara wa kii se kekere ta ba jẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n ba BBC sọrọ, onimọ nipa awọn ounjẹ asaraloore, Collins Akanno mẹnuba ọpọ awọn eso ati ewebẹ to wa ni arọwọto wa, amọ ti a ko naa rara.

Bi anfaani ara awọn eso ati ewebẹ naa se lọ ree:

Carrot:

Ti eeyan ba ra Carrot, to fọọ, ko yẹ ki a jẹ bẹẹ, amọ o yẹ ka se lori ina fun igba ranpẹ, ki eroja Vitamin A to wa ninu rẹ lee maa jade si ẹnu wa, ba ba se n jẹẹ.

Nitori naa, lati akoko yii lọ, maa se eso carrot rẹ, ko rọ diẹ lori ina, ki o to maa jẹ.

Isu:

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe ewebẹ ni eroja isu, ounjẹ lasan la mọ si.

Lootọ ni isu ni eroja afaralookun taa mọ si Starch ninu, amọ to ba fẹ jẹ isu, mase jẹ ki isu to jẹ kọja odiwọn ikuuku tabi ẹsẹ rẹ nigba kuugba to ba n jẹ isu.

Idi ni pe eroja afaralokun to jẹ nijoko ẹẹkan ko gbọdọ tobi ju deede ẹsẹ ọwọ rẹ lọ nitori eroja Starch to wa nibẹ.

Ewe Lettuce:

Ewe yii wulo fun mimu ki isan ara rọ, ko si ni ilera to peye.

Ẹnikẹni ti ara rẹ kii balẹ, to maa n re galegale, ti kii le duro si oju kan, tabi to jẹ oni iwanwara, to ba n jẹ ewe Lettuce, yoo ri pe irọrun ba agọ ara rẹ.

Koda, bi o ko ba ri oorun sun, iwọ sa ti jẹ ewe Lettuce, bi ọmọ tuntun jojolo lo sun fọnfọn.

Cucumber:

Eso miran to tun wulo fun isẹda ni eso Cucumber. Ọpọ obinrin to ba jẹ asaraloge, to si maa n setọju awọ ara wọn loore koore ni kii fi eroja Cucumber sere rara.

Bo se wulo fun itọju oju, taa ge wẹwẹ fi bo ẹyinju wa mejeeji, naa lo tun wulo fun irun ori obinrin.

Cucumber yii tun dara fun awọ ara ti yoo si mu ko maa dan yọyọ, ti yoo si mọ kedere. Bakan naa lo tun dara fun eekanna wa, ta ba si tun jẹ, se ni a ya awọn idọti kuro lagọ ara wa.

Avocado pear:

Eso pear wulo pupọ fun agọ ara wa, nitori o tun maa n mu adinku ba awọn ọra ara taa mọ si Cholesterol.

Yatọ si eyi, pear tun maa n se iranwọ fun tọkunrin-tobinrin to ba n wa ọmọ, eyi ti ko yẹ ki wọn maa fi sere rara.

Ko tan sibẹ o, eso yii tun jẹ ara eso ti ko se ko pamọ fun igba pipẹ, eyi to n mu ka maa jẹ eso rẹ ni ajaabalẹ.

Irufẹ eso ajaabalẹ yii wulo fun awọn eeyan ti ẹjẹ ara wọn ko to rara, ti eroja Iron to wa ninu rẹ yoo si tete mu ki ẹjẹ pọ lara wọn.

Awọn eso taa mẹnuba diẹ lara wọn yii wa larọwọtọ wa ati lawọn ọja wa gbogbo, nitori naa, ẹ maa ra wọn jẹ, kẹ si mase fi wọn sere rara.