Operation Positive Identification: Ilé aṣòfin-ṣojú ní Buhari gbọ́dọ̀ ká iléeṣẹ́ ológun lọ́wọ́ kò lórí àyẹ̀wò ìdánimọ̀

Awọn araalu kawọ soke niwaju ologun kan

Oríṣun àwòrán, Others

Ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko tete yara paṣẹ fun ileeṣẹ ologun lati jawọ lori igbesẹ ayẹwo ati idanimọ tawọn ologun fẹ gunle kaakiri orilẹede Naijiria.

Eto idaraẹnimọ, 'Operation Positive Identification' lawọn ologun sọ pe awọn gbe kalẹ, lati ṣawari awọn eeyan to ba wa lori iwe 'a-n-wa-ọ' awọn agbofinro, atawọn ajeji to wọ ilẹ yii lai gbawe aṣẹ iwọlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn aṣoju-ṣofin lero tiwọn ni igbesẹ naa tako agbekalẹ ofin Naijiria lori ojuṣe ileeṣẹ ologun gẹgẹ bi abala okoolelugba o din mẹfa iwe ofin ọdun 1999 ti wi.

Oríṣun àwòrán, Others

Nigba to n gbe aba lori ọrọ naa kalẹ, olori ẹgbẹ oṣelu to kere nile igbimọ aṣoju-ṣofin, Ndudi Elumelu ni igbesẹ naa kii ṣe ojuṣe ileeṣẹ ologun, ikọja aaye lasan ni.

Bakan naa ni aṣofin Toby Okechukwu ati Ahmed Jaha pẹlu woye pe, airiṣẹ ṣe lo n damu awọn ologun, paapaa awọn adari wọn.

Wọn ni bawọn adari ileeṣẹ ologun ko ba mọ ohun to kan fun idaabobo Naijiria, ki wọn yara fi ipo silẹ fun awọn adari tuntun ti ọpọlọ wọn n gba yagiyagi ni.

Ni ọjọ karundinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2019 lawọn ologun kede pe, awọn yoo fẹ eto naa loju de gbogbo tibutoro Naijiria lati "ka awọn agbebọn, ajinigbe, adigunjale, atawọn ajimaalu gbe lọwọ ko, kaakiri ẹkun gbogbo.