Ambode: Àwọn aṣòfin Eko kò le è wádìí mi, àwọn ló fòǹtẹ̀ lu owó tí mo ná

Ambode n jade ninu ọkan lara awọn ọkọ

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Sinima orita awoowo tan lọrọ iwadi ẹsun ajẹbanu to n waye laarin gomina ana ni ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde atawọn aṣofin ipinlẹ naa.

Ṣe ẹ mọ pe lọsẹ to kọja lawọn aṣofin ipinlẹ Eko paṣẹ pe ki Ambọde wa farahan niwaju ile naa ni Ọjọru ọgbọn ọjọ oṣu kẹwa lati wa wi tẹnu rẹ lori bi o ṣe na owo ti wọn ya sọtọ fun rira bọọsi bọgini akero BRT atawọn inawo akanṣe iṣẹ miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi awọn aṣofin ipinlẹ Eko ṣe n lọgun pe Ambọde ko tẹle ofin lori inawo rira ọkọ naa, ni Ambọde pẹlu n pariwo tan-tan-tan ni tirẹ pe, ṣe awọn aṣofin ipinlẹ Eko lẹ ṣingọọmu moju ni, nigba ti wọn n buwọlu owo fun rira awọn ọkọ bọọsi bọgini akero naa labẹ eto iṣuna ọdun 2018?

Koda, olori ile naa Mudashiru Ọbasa tilẹ fọwọ lalẹ pe, bi Ambọde ko ba farahan niwaju ile naa, aṣẹ ẹ fi kele ofin gbe lawọn yoo pa ki wọn fi gbe e.

Amọṣa, kaka ki Ambọde farahan, ile ẹjọ lo gba lọ toun ti lọya rẹ, Tayọ Oyetibọ, SAN lati gba iwe ile ẹjọ ti yoo ka awọn aṣofin ipinlẹ Eko lọwọ ko lori ohun ti wọn fẹ ṣe naa.

Oríṣun àwòrán, @lshaofficial

Adajọ si ti ni ki Ambọde o fi iwe ipẹjọ atawọn iwe miran gbogbo to rọ mọ ẹjọ naa naa, wa awọn aṣofin naa lọ.

Awọn ti Ambọde pe ko wa jẹjọ lori ọrọ naa bayii ni olori ile aṣofin ipinlẹ Eko, Mudashiru Ọbasa, akọwe agba ile aṣofin ipinlẹ Eko, A.A. Sanni.

Bakan naa lẹjọ tun kan awọn ọmọ igbimọ ti wọn gbe kalẹ lori rira ọkọ bọọsi naa, iyẹn họnọrebu Fatai Mojeed, Gbolahan Yishawu, A.A. Yusuff, Yinka Ogundimu, Mojisola Meranda, M.L. Makinde, Kehinde Joseph, T.A. Adewale pẹlu O.S. Afinni.

Oríṣun àwòrán, @AkinwunmiAmbode

Ambọde ni, n ṣe lawọn aṣofin ipinlẹ Eko mọọmọ n yi iwe ati akọsilẹ lori rira okoolelẹgbẹrin ọkọ bọọsi bọgini akero naa, gẹgẹ bi o ṣe wa ninu iwe ofin iṣuna ipinlẹ Eko ti ọdun 2018 eleyi tawọn aṣofin ile naa fọwọ si funrawọn.

Ṣe ẹ ri pe kannakanna n'ọmọ ẹga, ija lori ọrọ naa ṣẹṣẹ n bọ ni, ko tii de.