Schistosomiasis: Ibà fà bí ìgbín wọ ìpínlẹ̀ Eko torí ẹ̀gbin omi, wo ohun tó ń fà á

Aworan ayẹwo ẹjẹ kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin iwadii kan eyi ti ileeṣẹ eto ilera tijọba ipinlẹ Eko ṣe ti fi idi rẹ mulẹ pe, ijọba ibilẹ mẹfa nipinlẹ Eko ti lugbadi ọwọja arun fa bi igbin, ti oloyinbo n pe ni Schistosomiasis.

Wọn ni aisi imọtoto to peye ati omi ti ko mọ lo n fa awọn arun yii.

Awọn ijọba ibilẹ ti wọn ni ọrọ naa kan ni Mushin, Alimọṣọ, ikẹja, Ibẹju Lekki, Agege ati Koṣọfẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyi ni awọn koko ti o yẹ ki ẹ m nipa arun yii:

 • Orukọ miran ti wọn tun maa n pe arun yii ni iba fa bi igbin (Snail fever)
 • Arun Schistosomiasis jẹ arun ti o n waye nipasẹ awọn kokoro arun kan to fara sin sinu omi
 • Ifun tabi ile itọ ni aisan yii maa n ba ja ni agọ ara
 • Lara awọn ohun to maa n farahan ninu agọ ara ẹni to ba ni aisan yii ni inu rirun, igbẹ gbuuru, igbẹ ẹjẹ tabi ki ẹjẹ maa fara han ninu itọ eniyan
 • Laarin awọn ọmọde ni aisan yii ti maa n wọpọ paapa julọ lawọn orilẹede to ṣẹṣẹ n goke agba nitori awọn lo maa n fara kan awọn omi, paapaa omi ti kokoro arun yii ba wa
 • Lara awọn ohun ti kokoro arun yii ma n ṣe lagọ ara awọn to mu ni biba kindinrin jẹ, biba ẹdọ jẹ, airọmọ bi ati jẹjẹrẹ inu ile itọ
 • Ni agọ ara awọn ọmọde, o lee fa idiwọ fun idagbasoke wọn, ati iṣoro nipa ẹkọ kikọ
 • Inu omi odo ni kokoro arun yii ti maa n jaye. Ara awọn ọna ti kokoro arun yii n gba wọ ara
 • Lasiko iṣẹ ọgbin, iṣẹ ile, iṣẹ oojs atawọn ere ojojumọ eleyi ti o mu eeyan fara kan awsn omi to ba ti lugbadi kokoro arun yii
 • Ohun ti o maa n fa arun yii naa ni aisi imọtoto paapaa nipa omi pẹlu ibi iṣere awọn ọmọde bii omi odo ti wọn ti n luwẹ tabi pa ẹja
 • Lara awọn ọna ti a lee gba dawọ aisan yii duro ni ipese omi to ja gaara, eto imọtoto to ye kooro, ati mimojuto bi awọn igbin ṣe n ni anfani lati farakan eeyan
 • Iwadii ajọ ilera agbaye fihan pe ni ọdun 2017 tii ṣe ọdun meji sẹyin, okoolelugba miliọnu eeyan lo ti ko aarun yii lagbaye, ninu eyi to jẹ pe mejilelọgọrun ti gba itọju.