EFCC: Ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè pé báwo ní àjọ náà ṣé mọ èké babaláwo?

Aworan Babalawo

Oríṣun àwòrán, EFCC

Babalawo kan, Fatai Olalere Alli, ti inagijẹ rẹ n jẹ baba Osun to tasẹ agẹrẹ sofin, tọwọ sinkun ajọ EFCC si baa, ni adajọ kan nile ẹjọ giga nilu Ibadan ti ni ki wọn lọ fi si ahamọ.

Ajọ EFCC to fi isẹlẹ naa sita loju opo Twitter rẹ tun kede pe bakan naa tun ni oun ko awọn eeyan meji mii, Adigun Fatai Olusegun ati Olufemi Kolawole sahamọ.

Ajọ EFCC fikun pe adajọ tun faye gba oun lati gbẹsẹ le awọn ile kan to jẹ ti babalawo naa ati akoto owo ti wọn lawọn fura si pe o fi n ṣe gbajuẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi ọhun ni pe wọn lẹdi apo pọ lati gba owo lọna ti ko tọ, eyi taa mọ si 419.

Bawo ni EFCC ṣe mọ pe ayederu babalawo ni?

Ibeere yii lawọn eeyan n beere loju opo Twitter EFCC, lati fesi si ikede iroyin ti wọn fi sita naa.

Lara awọn to beere ọrọ yii la ti ri eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ North Boy, to ni bi babalawo naa ba jẹ ojulowo, ṣe EFCC yoo lawọn o mu?

Ni ti tiẹ, Klaus ni ṣe ẹṣẹ ni ki awọn irunmọlẹ ma gbe owo fun eeyan ni?

Skala wee tilẹ ni bi babalawo naa ba ni agbẹjọro to munadoko, kia ni yoo jaja bọ lọwọ EFCC.