Lagos Police: Davido tasẹ́ agẹ́rẹ́ lórí àwọn obìnrin tó sọ panpẹ sí lọ́wọ́

Aworan Davido

Oríṣun àwòrán, Instagram/davidoofficial/specialspesh

Àkọlé àwòrán,

Davido ti pada ni ki wọn tu awọn obinrrin naa silẹ ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ni o lẹjọ ro lọdọ awọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa nilu Eko ti bẹnu atẹ lu gbajugbaja akọrin takasufe Davido pẹlu bi o ṣe paṣẹ ki wọn sọ panpẹ sọwọ awọn obinrin kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Bala Elkana to sọ ọrọ yi fun ile iṣẹ BBC ni ofin ko faye gba ki ọlọdani sọ mamugari seeyan lọwọ depo pe yoo tun ṣafihan wọn bi ọlọpaa ṣe n ṣafihan ọdaran.

Ninu fọnran fidio kan ti o ṣafihan awọn obinrin meji kan ti wọn sọ panpẹ si lọwọ, ọkan lara awọn ọmọ iṣẹ Davido n beere ọrọ lọwọ awọn obinrin naa.

Oju opo Instagram ni ọkan lara awọn to n gbẹnu sọ fun Davido fi fidio yii si to si ti mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Elkana sọ pe awọn ko mọ si bi wọn ti ṣe mu awọn obinrin naa ati pe ko tọ ki Davido paṣẹ ki wọn mu wọn botilẹjẹwipe o fẹsun kan pe wọn parọ mọ.

O ni laipẹ yi awọn yoo kan si Davido ko wa ṣalaye tẹnu rẹ lori fọnran fidio yii.

Ofin Naijiria mẹta niDavido tapa si

Nigba ti a kan si alakoso ẹka ijọba to n gbeja ara ilu (OPD) arabirin Yinka Adeyemi, o ni ofin ilẹ Naijiria mẹta ni Davido tasẹ agẹrẹ si to ba ṣe pe o mọ si fidio naa.

''Akọkọ ibẹ ni pe o gba iṣẹ ọlọpaa ṣe pẹlu bi o ti ṣe mu eeyan fun ara rẹ, ẹlẹẹkeji ni pe o tabuku ba ọmọlakeji rẹ ti ẹlẹkẹẹta si jẹ pe o fipa mu eeyan miiran silẹ lalai ṣe agbofinro''

Oríṣun àwòrán, Facebook/OPD-LAGOS

Arabinrin Adeyemi sọ pe oun to yẹ ni ki awọn agbofinro pe Davido ko wa sọ ohun to ri lọbẹ to fi garu ọwọ.

Iru iwa bayi gẹgẹ bi o ti ṣe sọọ lodi si ofin ti ko si yẹ ki a fi aaye gba iru iwa bẹẹ lawujọ.

O wa parọwa si awọn ti wọn mu yii lati tọ awọn wa ti wọn ko ba mọ ọna ti wọn yoo fi pe Davido lẹjọ.

Bawo ni ọrọ naa ti ṣe rin?

Ni nkan bi ọjọ melo kan sẹyin ni ọrọ yi jẹyọ.

Awọn obinrin meji kan ni wọn ṣadede fi fidio si oju opo ayelujara nibi ti wn ti ni Davido fun ọkan ninu wọn loyun.

Iroyin tan kaakiri ti awọn eeyan si n ṣemo pe iru nnkan wo leleyi.

Fọnran fidio tawọn obinrin naa ti fẹsun kan Davido ree.

Bi Davido ti ṣe halẹ mọ wọn pe oun yoo sọ wọn si ẹwọn ni wọn jade sita pẹlu fidio miiran pe awada ni awọn n ṣe.

Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ nitori Specialspesh to jẹ ọkan lara awọn alukoro Davido fi ikede soju opo Instagram to sọ pe oun ṣetan lati gbe miliọnu naira kan kalẹ fẹni to ba le ṣatọka awọn obinrin to n parọ mọ Davido loju opo ayelujara.

O ni awọn fẹ ki wọn foju wina ofin lori nkan ti wọn ṣe yii.

Oríṣun àwòrán, Instagram/specialspesh

Abalọ ababọ ijiya ti specialspesh fẹ fi jẹ wọn lo ja si fọnran fidio ibi ti wọn ti mu awọn obinrin mejeeji ti wọn si sọ panpẹ si wọn lọwọ.