Corporal Punishment: Olùkọ́ fẹgba lu akẹ́kọ́ọ̀bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá pa ní yàrá ìkàwé

Olukọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agba adura ni pe ki abiyamọ ma foju sọkun ọmọ laye. N jẹ ẹ ti ri ibi ti olukọ ti fẹgba lu akẹkọọ pa ri?

Ohun to ṣẹlẹ gan gan ree niluu Bujumbura tii ṣe olu ilu orilẹede Burundi.

Chadia Nishimwe, akẹkọọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla ni baba rẹ sọ fun BBC pe o jẹ Ọlọrun ni pe lẹyin ti olukọ kan lu u lalubolẹ.

Jean-Marie Misago ṣalaye fun BBC pe olukọ naa to ẹgba si ọrun ati ẹsẹ Nishimwe debi wi pe, o n yọ ẹjẹ ni imu ati eti rẹ.

Misago sọ pe ọmọ oun ku ninu yara ikawe lẹyin ti olukọ yii na a tan, koda ọfiisi ọga ile iwe ọhun ni wọn gbe oku rẹ si.

Ọga ile iwe gbiyanju lati gbe Chadia lọ si ile iwosan, amọ, ẹpa ko boro mọ lẹyin ti dokita sọ fun un pe ọmọ naa ti ku ki wọn to gbe e de.

Misago ni ọjọ Iṣẹgun l'oun sin ọmọ naa, ọjọ kan naa ti ọmọ yii ku.

Ohun ti wọn sọ fun baba ọmọ yii ni pe Chadia tapa si ofin kan to de awọn akẹkọọ ninu yara ikawe rẹ.

Ofin orilẹede Burundi ko faaye gba ifiyajẹni tabi fifi ẹgba lu'yan.

Àkọlé fídíò,

Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN