Mobolaji Johnson: Olùfọkànsìn ilẹ̀ Nàìjíríà ni gómìnà àkọ́kọ́ ìpínlẹ̀ Eko - Sanwo-Olu

Aworan Omobolaji Johnson ati Muhammad Ali

Oríṣun àwòrán, Facebook/Deji Johnson

Àkọlé àwòrán,

Awọn to mọ Mobolaji Johnson nigba aye rẹ ni o jẹ ọlọyaya

Bi a ba pe ori akọni Mobolaji Johnson,niṣe laa o ma fi ida lalẹ garara.

Ni bayi to ti dagbere faye pe o digba,awọn ohun to gbe ṣe laye ni a o ma fi ranti rẹ.

Ninu awọn ohun to ṣe la ti ri eleyi ti awọn eeyan n gbe oṣuba fun ati awọn miran ti awọn ẹlomiran ni o ku diẹ kaato.

O ṣàkóso manigbagbe mí tó ṣé

Amọ ṣa ki a to ṣe atupalẹ awọn nkan wọn yi,o tọ ki a ṣalaye pe Mobolaji Olufunso Johnson ni Gomina ologun akọkọ ti wọn yan ni ipinlẹ Eko laarin oṣu kaarun ọdun 1967 titi di oṣu Keje ọdun 1975.

Ọmọ Ẹgba ni Mobolaji Johnson ti a si bi ni ọdun 1963.

Lasiko igba to jẹ Gomina labẹ ijọba Yakubu Gowon o ṣe awọn nkan orisirisi to jọ mọ idagbasoke ilu.

Pataki ninu ohun ta ri akọsilẹ pe o ṣe ni ṣiṣe agbekalẹ ilana fawọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Deji Johnson

Àkọlé àwòrán,

Awọn to mọ Mobolaji Johnson nigba aye rẹ ni o jẹ ọlọyaya

Bakanna, o ṣe agbekalẹ ofin kan to koju bi awọn onile ti ṣe n gbowo gọbọi lori ile wọn.

Lasiko ta n sọ yi,ijọba da awọn kootu ti yoo ma dajọ lori iye owo tawọn onile n gba lọdọ ayalegbe.

Ofin yi fi igba kan dẹwọ gbigbe ile kalẹ lowo gọbọi titi di asiko tawọn eeyan bẹrẹ si ni ṣe eleyi to wu wọn.

Eko Bridge

Lasiko ti Mobolaji jẹ Gomina ipinlẹ Eko ni wọn bẹrẹ si ni kọ afara ẹlẹẹkeji si erekusu Eko(Eko Bridge)

Awọn eeyan kan sọ pe asiko rẹ ni wọn bẹrẹ iṣẹ lori afara ẹlẹẹkẹta to lọ si erekusu Eko(Third Mainland Bridge )ṣugbọn a ko ri idi ọrọ yi fi mulẹ botilẹjẹwipe ọdun 1990 ni wọn si afara naa.

Iboji oku Ajele

Lara awọn nkan ta ri akọsilẹ pe ọgagun Mobolaji Johnson ṣe nigba aye rẹ ni pe o paṣẹ ki wọn tu iboji oku ti wọn sin ni Ajele ka ti wọn si ko awọn oku ibẹ kuro.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr Raphael James

Àkọlé àwòrán,

Arakunrin Raphael James nibi to ti duro lẹgbẹ iboji ti wan pada sin oku Samuel Ajayi Crowther si

Lọdun 1971 lo paṣẹ yi toripe wọn fẹ kọ ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko sibẹ.

Igbesẹ yi jẹ eleyi tawọn eeyan bẹnu atẹ lu ti a si gbọ pe Samuel Ajayi Crowther ati awọn eekan mi bi Iyaafin Efunroye Tinubu wa lara awọn oku ti wọn wu kuro nibẹ.

Awọn nkan miran ti o jẹ manigbagbe nipa rẹ:

Nigba ti ijọba ologun Murtala Muhammed de ori oye mi 1975,ọgagun Mobolaji Johnson ati ọgagun Oluwole Rotimi nikan ni Gomina meji ti igbimọ ẹlẹni mẹta ti wọn gbe kalẹ sọ pe wọn ko jẹbi iwa ajẹbanu.

Ọdun 1975 ni Mobolaji Johnson fẹyinti nidi iṣẹ ologun ti o si bẹrẹ iṣẹ aladani ti rẹ.

Oríṣun àwòrán, Uyi Obaseki

Àkọlé àwòrán,

Ọgagun Mobolaji Johnson lo wa lapa ọtun aarẹ ologun igba naa Yakubu Gowon lọdun 1972

Loni bayi,wọn fi opopona ati aye eye idaraya pe orukọ rẹ.

O jẹ ẹni to fẹran ere idaraya ti o si nifẹ si irrinajo inaju.

Ẹwẹ, Gomina Babatunde Sanwo-Olu ti ranṣẹ ibanikẹdun si idile oloogbe Mobolaji Johnson.

Sanwo-Olu ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi olugbe ilu Eko to ṣiṣẹ takuntakun fun igbega ipinlẹ ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

Sanwo-Olu sọ pe ijọba Mobolaji Johnson lo pese oniruuru nnkan amaludẹrun nipinlẹ Eko, eleyi to si tun wa doni.

Gomina ipinlẹ Eko ni lootọọ ni Mobolaji Johnson ti filẹ ṣaṣọbora, amọ, awọn eeyan yoo maa ṣe iranti rẹ lọ laelae nitori awọn iṣẹ nla nla to gbese nigba aye rẹ.

Sanwo-Olu ni ''gbogbo eeyan lo ranti bi ijọba Mobolaji Johnson ṣe kọ ile iwe girama marun un ati ọpọ ilegbee laarin ọdun kan ijọba rẹ.''

Gomina ipinlẹ Eko ni ọna kan gboogi lati maa ṣeranti Mobolaji Johnson ni lati rii pe awọn araalu n jẹ anfaani ijọba awarawa.

O dagbere fayẹ lọgbọn ọjọ oṣu Kẹwa ọdun 2019 lẹni ọdun mẹtaleọgọrin.

Àkọlé fídíò,

Àṣà àti ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé òbí wọn máa ń padà wá sáyé