Oshiomole: Nínú ká máa rin ìrìnàjò ilẹ òkèèrè, ọgá ṣí ní Ọbasanjọ jẹ́

Adams Oshiomhole

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Oshiomole: Nínú ká máa rin ìrìnàjò ilẹ òkèèrè, ọgá ṣí ní Ọbasanjọ jẹ́

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ti sọ pe lootọ laarẹ Muhammadu Buhari le ma rin irinajo lọ si ilẹ okeere ṣugbọn lori agbelewọn ko ti ṣe to aarẹ ana,Olusegun Obasanjo.

Opọ awọn ọmọ Naijiria ti n sọrọ pe ko si koko pe Aarẹ Buhari n rin irin ajo kaakiriBuhari kàn ń kọwọ́ bọ̀wé nílẹ̀ òkèèrè kiri ni, a ò rí ipa ní Nàijíríà- Onímọ̀ ọrọ̀-ajé

Oshiomole fesi yi ni idahun si ibeere awọn oniroyin l'Abuja lori bi aarẹ Buhari ti ṣe fẹran lati ma rinrinajo lọ silẹ okeere lasiko yii.

Alaga ẹgbẹ APC naa sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ yi.

Lati le kin ọrọ rẹ lẹyin, o ni Gani Fawehinmi kọ iwe kan nibi to ti ṣatupalẹ iye igba ti aarẹ Obasanjo fi ririn ajo nigba to wa ni ijọba.

Oshiomole ni ''Ki a ma sọ pe aarẹ Buhari fẹran ko maa rinrin ajo lọ si ilẹ ki i ṣe ootọ.

Mo ranti daadaa pe ko si aarẹ kankan lati ọdun 1999 titi di isinyi to rinrin ajo to aarẹ ana Olusegun Obasanjo''

Loju Oshiomole, irinajo Buhari ko tii pọ ''Bi ẹ ba wo akọsilẹ daadaa, ẹ o ri ibi ti oloogbe Gani Fawehinmi ti ka iye igba ti aarẹ Obasanjo ti lọ irinajo silẹ okeere. Koda o ka iye wakati to n lo lori ofurufu pẹlu iye igba to fi wa nile''

Lẹnu ọjọ mẹta yii, aarẹ Muhammadu Buhari ti n ṣe awọn irinajo lọ si ilẹ okeere eleyi to mu ki awọn ma sọrọ pe kii joko sile ṣejọba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: