Nollywood: Taiwo Hassan, akọni òṣèré Yollywood tó jẹ́.....

Ogogog

Oríṣun àwòrán, @Ogogo

Àkọlé àwòrán,

Opọ eniyan lo n ba ọlọjọ ibi yọ ayọ ọgọta ọdun

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria lo n ki agba oṣere Taiwo Hassan ku oriire ọgọta ọdun lori oke eepẹ loni.

Yinka Quadri to jẹ ọrẹ ti wọn ti jọ n ṣere tipẹtipẹ naa kii pe ọrẹ to yatọ ni Ogogo jẹ

Opolopo awọn ololufẹ BBC naa n gboriyin fun Ogogo Kulodo ti wọn si n sọrọ nipa awọn ere Taiwo Hassan ti wọn gbadun julọ loju opo BBC News lori facebook.

Àkọlé àwòrán,

Eni ọdun ba ba laye a ṣọpẹ paapaa to ba huwa ti aye n ri sọ nipa rẹ

Àkọlé àwòrán,

Loju opo Facebook BBC News ni awọn eeyan ti n sọrọ nipa awọn ere Ogogo

Àkọlé àwòrán,

Iya Ibeji, Eleran Igbẹ atawọn

Taiwo Hassan, akọni òṣèré Yollywood tó jẹ́.....

Wo ǹkan márùn ún ti ò kò mọ̀ nípa Taiwo Hassan, Ogogo ọmọ kulodo tó n ṣeré Yorùbá.

A bi Taiwo Hassan ti gbogbo eeyan mọ si Ogogo ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun 1959.

Ilu Ilaro ni ipinlẹ Ogun ni guusu iwọ oorun Naijiria ni ati bi Ogogo ọmọ Kulodo.

Oríṣun àwòrán, @Ogogo

Àkọlé àwòrán,

Taiwo Hassan to jẹ Denzel Washington inu ere agbelewo Yoruba!

Oṣere ti igba oju mọ ni Taiwo Hassan, o ti ṣe awọn ere to lokiki bii Owo Blow, Sababi, Ibinu elewọn, Atitẹbi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò,

Adedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Odindin ọdun mẹtala ni Taiwo Hassan fi ṣiṣẹ pẹlu ẹka to n mojuto omi ẹrọ ni ipinlẹ Eko.

Odun 1994 ni Ogogo fẹyinti kuro lẹnu iṣẹ Oba ipinlẹ Eko ko too gbajumọ ere ṣiṣe ni ẹkunrẹrẹ.

Taiwo Hassan lọ sile iwe alakọbẹrẹ Christ Church School nilu Ilaro.

O tun ló sile iwe Yaba Technical College nibi to ti kọ ẹkọ nipa ọkọ titunṣe.

Àkọlé fídíò,

'Oun tí Kunle Afolayan ṣe sí mi, mi ò lè ṣeé sí i'

Ogogo fẹ obinrin meji ọtọọtọ.

Taiwo Hassan bi ọmọbinrin mẹta ati ọmọkunrin kan.

Odun 1981 ni Taiwo Hassan bẹrẹ iṣẹ ere ṣiṣe ni kete to bẹrẹ iṣẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko.

Ogogo ni idi ti oun fi n duro deedee bi ọmọkunrin ni ere idaraya ẹṣẹ kíkàn ti oun gbadun lati maa ṣe fi daraya.

Bakan naa lo tun ni oun fẹran lati maa gbọ orin paapaa ti awọn ọdọ iwoyi to ba mọgbọn dani

Àkọlé fídíò,

Njẹ ọkunrin nilo isinmi nigba ti iyawọ wọn ba sẹsẹ bi ọmọ?

Ogogo jẹ ọkunrin ti o ni awọn iwa kan to yaa sọtọ lagbo oṣere.

Ninu ifọrọwerọ kan lo ti ṣalaye pe oun kii fẹnuko obinrin lẹnu ninu ere nitori ko si lara abuda adamọ oun.

Ogogo ni oun ko fi bẹẹ fẹran lati maa ṣe ipa ololufẹ to n fi ifẹ han ni gbangba ninu ere agbelewo.

Àkọlé fídíò,

Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi